Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 6, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà wà ní ìpàdé pàtàkì ní Washington lórí ọ̀rọ̀ ààbò àti òmìnira ẹ̀sìn, lẹ́yìn tí ìjọba Donald Trump fi Nàìjíríà sí ipò “Country of Particular Concern”.
Olùdámọ̀ràn Ààbò Orílẹ̀-èdè (NSA) Nuhu Ribadu ni ó ṣáájú àwọn aṣojú Nàìjíríà lọ sí Ẹgbẹ́ Ìṣiṣẹ́ Àpapọ̀ Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà, nígbà tí Allison Hooker, Under Secretary fún ọ̀rọ̀ òṣèlú Amẹ́ríkà ló ṣáájú ẹgbẹ́ Amẹ́ríkà.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
Ìpàdé náà dá lórí ìgbésẹ̀ lòdì sí ìpayà jẹmìjẹmì, ìlọsíwájú nínú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìgbésẹ̀ tó kàn fún orílẹ̀-èdè méjèèjì. Ìpàdé ààbò ọ̀tọ̀ mìíràn yóò wáyé ní ọjọ́bọ̀.
Àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ Nàìjíríà ní: IGP Olatunji Disu, Minisita fún Ọ̀rọ̀ Òde Bianca Odumegwu-Ojukwu, Minisita Ààbò Christopher Musa, Minisita fún Owó Taiwo Oyedele, Minisita fún Ọ̀rọ̀ Ilé Olubunmi Tunji-Ojo, AGF Lateef Fagbemi, Sola Enikanolaiye, CDS Gen. Olufemi Oluyede àti Jimoh Ibrahim.
Ìpàdé yìí ni ìtẹ̀síwájú àwọn ìpàdé tó ti wáyé láti mú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ààbò lágbára síi àti láti dáhùn sí àníyàn Amẹ́ríkà lórí òmìnira ẹ̀sìn.
