Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Abameta, 19, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Gbajugbaja oṣere Nollywood ilẹ̀ wá nnì, Arabinrin Toyin Abraham tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ ń pè ní Mummy Ire lo ti jáde sọ̀rọ̀ ni ìgboro ayé nípa aheso ńlá kan tí àwọn kan ń gbé káàkiri lórí ayélujára pé òun o sì lọdọ ọkọ òun mọ, tí òun náà jẹ irawo osere bí ti ẹ Arákùnrin Kolawole Ajeyemi mọ

Nígbà tí Mummy Ire bí àwọn tí ẹ ṣe ń pè ń sọ̀rọ̀ lórí aheso ọrọ naa loti sọ fún gbogbo ayé pé àdéhùn ayérayé lóhùn àti ọkọ òun jọ ní, àti pé orí òun kò, Ẹlẹda òun kò kiko kúrò lọdọ ọkọ òun àti pé òun mimọ pé àwọn ọta ilọsiwaju òun lowa nìdí ọrọ naa, , ori wa kọ ọ, ẹlẹdaa wa kọ ọ.”
Esi Toyin Abraham ṣafihan pe ahesọ ọrọ lasan ni iroyin ati pe irọ to jina si ootọ ni pe igbeyawo wọn n koju wahala tabi pe awọn mejeeji ti pinya.

Agba oṣere naa tun kọ pe ipinya ko si ninu irinajo oun ati ọkọ oun nitori oun ko gbadura fun ituka laaarin oun ọkọ oun ati pe oun n fi adura jagun fun idile naa.
Igba akọkọ kọ niyi tawọn tọkọtaya naa yoo ma kojun irufẹ iroyin bayii.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ọpọ igba ni wọn ti gbe iroyin pe igbeyawo Toyin ati ọkọ rẹ, ti oun naa jẹ agba oṣere, ti fori ṣọpọn ṣugbọn ti awọn ololufẹ mejeeji yoo tako iroyin bẹẹ.

Ni ọdun 2019 ni Toyin ati Kolawole ṣe igbeyawo ranpẹ ni ilana ibilẹ lẹyin ti awọn mejeeji ti ṣe ọrẹ fun ọpọ ọdun lagbole ere sinima Yoruba.
Lẹyin igbeyawo naa ni tọkọtaya ọhun bi ọmọ ọkunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Ire.

Ṣaaju igbeyawo naa ni Kolawole ti bi ọmọbinrin kan eyi ti Toyin maa n pe ni akọbi rẹ, to si maa n sọ pe ọmọ meji ni Ọlọrun fi kẹ igbeyawo awọn.

One thought on “ORÍ MI KO, ÀDÉHÙN AYÉRAYÉ LEMI AT’ỌKỌ̀ MÍ ṢÉ, – Toyin Abraham”