Ọlọ́run ṣeun ó! LASCOPA GBÀ OWO T’OLE NI MILIONU MERINDINLOGBON FÚN ÀWỌN ONIBA’RA IKEJA ELECTRIC

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolanle Kareem, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Ẹti, 30, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Ajo to n daabobo awon onibara ni Ipinle Eko, LASCOPA, ti gbe igbese nla lati daabobo ẹtọ awon to n lo ina Ikeja Electric, nibi ti won ti yanju ejo 528 ti awon onibara fi sun, ti won si tun gba owo isanpada ati atunse owo ina to je ₦26,243,758.75 pada fun awon eniyan laarin osu kini si osu kesan odun 2026.

 

Gẹgẹ bi akosile ajo naa, lapapọ ejo 556 ni won gba lodi si Ikeja Electric (IKEDC) ni osu mesan naa. Ninu eyi, 528 ni won ti yanju, o ku 28 ti o wa lọwọwọ, eyi ti o tumo si pe bi 95% ninu awon ejo naa ni won ti yanju.

 

Oludari Agba / Alakoso Agba LASCOPA, Afolabi Solebo, Esq., tun tẹnumọ ifaramo ajo naa si didojuko aiṣododo, jijawo awon ileese ina, ati rii daju pe iṣẹ ti o dara de ọdọ awon araalu.

Àwọn igbimọ oludajo ni LASCOPA

Bi won se n yanju oro náà rèé 

Olori Eka Ejo ati Ilaja ti LASCOPA, Mr. Yusuf Musiliu, salaye pe ajo naa n gba ejo nipa ona ori ayelujara ati ni ọfiisi. O ni apejọ ti won n se pẹlu Ikeja Electric ni gbogbo Ọjọbọ to kẹhin oṣu kọọkan ni aye ti awon onibara ati oṣiṣẹ IKEDC ti n jiroro, ti n de adehun alafia.

O gba awon onibara nimoran pe ki won ma lo iwa-ipa tabi gige okun waya, ki won tẹle ilana to tọ. O ni ki won fi awon iwe eri silẹ bi:

 

*Bilii ina

*Risiti owo ti won san

*Ẹri miiran

Àwọn ọmọ igbimọ olùṣàkóso àjọ LASCOPA ni ipinlẹ Èkó

Lati le yara yanju oro naa.

Iwadii OJB News Yorùbá:

Iwadii wa fihan pe eyi kii ṣe igba akọkọ. Ni ọdun to kọja, LASCOPA tun gba to ₦186m ni atunse owo bill fun awon onibara Eko lapapọ ninu ẹgbẹrun ejo ti o jẹmọ overbilling ati oro transformer.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ṣé lóòótọ́ nipe ilé igbimọ aṣofin orile-ede Naijiria ń gbìyànjú láti dá àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mìíràn silẹ kún eyii tí ó wà nílè,. *Eyii ni òun ti a mọ nípa rẹ bí àwọn kan ṣe ń sọ pẹlu ó ní ọwọ òṣèlú nínú ni

Wàhálà ńlá rèé bí àwọn ẹbí gbajugbaja olórin T’oluwani Sings ṣe kó láti sìn òkú ọmọ wọn, tí wọn ní dandan ni ki awọn ó ṣe ìwádìí ikú tó pa. *Wọn ní ń ṣe ní wọn ń jẹun tí wọn ń yọ bí pé nnkan-kan ó ṣẹlẹ̀ lọjọ tí wọn lọ sile rẹ….

Iroyin yi fihan pe ijọba Eko n tẹsiwaju lati fi agbara mu Ofin Idaabobo Onibara ti Ipinle Eko 2025 wá sí ìmúṣẹ (atunse).

 

LASCOPA tun rọ awon araalu ti o ni ejo lori:

*Owo ina ti o pọju (overbilling / estimated billing)

*Aisi ina to pe

*Iwa aiṣododo miiran lati ọdọ ileese ina

 

Ki won pe Nọmba ọfẹ: 080 0005 2726 ni ọjọ aje ọsẹ, tabi ki won kọ imeeli si: lasgcopa@gmail.com

Ejo yin yoo gbo, ẹtọ yin yoo bọ!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.