Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aiku, 4, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ija dù agbara ti bẹ silẹ lori pẹpẹ ija ere ìdárayá ẹsẹ kiikan Chaos In The Ring ti Balmoral Promotions ṣeto ni Federal Palace Hotel, Victoria Island, Eko, ni ọjọ kini, oṣu kẹwa, ọdun 2026.
Ninu ere naa, ayẹyẹ Phyna ati apanilẹrin Carter Efe ni wọn ja bori ninu ere boxing ti awọn gbajumọ, nigba ti ọmọ orilẹ-ede Ghana, Seth “Freezy Macbones” Gyimah gba igbanu WBO African Light Heavyweight lọwọ Godday “Zodsolo” Appah.

PHYNA KO ITAN TUNTUN – O LU NKECHI NI ALU BOLẸ
Josephina Otabor, ti gbogbo eeyan mọ si Phyna, to jẹ aṣaju Big Brother Naija tẹlẹ, lu oṣere Nollywood, Nkechi Blessing lulẹ pẹlu Knockout ninu ere ti wọn ṣe fun ija mẹrin.
Pẹlu iṣẹgun naa, Phyna di obinrin akọkọ ti o ja bori ninu ere boxing awọn gbajumọ obinrin ni Naijiria.
Lẹyin ija naa, Phyna sọ pe oun fẹ ba oṣere miran, Etinosa Idemudia, ja.
O ni:
“Mo wọle, mo ṣe iwọntunwọnsi mi, mo si ṣe ohun ti mo wa lati ṣe. Bayi mo fẹ ba Etinosa ja. O to akoko ki n kọ ọ ni ẹkọ.”
Etinosa ti o wa lori pẹpẹ ti n wo bi Phyna ṣe lu Nkechi lulẹ, gba ipenija naa lẹsẹkẹsẹ. O ni, “Mo ti n gba ọ nimọran ki o gbe orukọ Edo larugẹ. A ki i sa fun ija kankan. Mo gba ipenija naa patapata.”
Phyna gba ẹbun owo Milionu Aadọta Naira (₦50m) gẹgẹ bi aṣaju, o si sọ pe oun fẹ tẹsiwaju ninu iṣẹ boxing gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ. O ni iṣẹgun lori Nkechi le jẹ ibẹrẹ iṣẹ tuntun fun oun.

CARTER EFE TUN JA BORI – O LU SPEED DARLINGTON
Ninu ere awọn gbajumọ keji, apanilẹrin Carter Efe ṣakoso orinrin Speed Darlington lati ibẹrẹ de opin ninu ija iyipo mẹrin, o si ja bori pẹlu Technical Knockout nigba ti Speed Darlington ko le gbe ara rẹ mọ.
Iṣẹgun naa mu ki Carter Efe tẹsiwaju ninu iṣẹgun rẹ laisi ikuna ninu ere Chaos In The Ring.
Efe ti ja bori olorin Habeeb “Portable” Badmus tẹlẹ ni ọjọ kini, oṣu karun, ọdun 2026 ni Balmoral Hall, Federal Palace Hotel, pẹlu idajọ gbogbo awọn onidajọ mẹtẹẹta 30-27.
Aifọkanbale ti bẹ silẹ laarin Carter Efe ati Speed Darlington ṣaaju ere naa, pẹlu ọrọ lile ti wọn n sọ fun ara wọn, titi ti wọn fi yanju rẹ lori pẹpẹ ija.

ERE AKỌKỌ: GHANA GBA BẸLITI LỌWỌ NAIJIRIA
Ninu ere akọkọ ti ọjọ naa, Godday Appah pẹnu igbanu WBO African Light Heavyweight rẹ fun ọmọ Ghana, Seth Gyimah, ti o ja bori pẹlu idajọ gbogbo awọn onidajọ.
Ere naa pò awọn oṣere, awọn akọrin, ati awọn afẹṣẹja akọṣẹmọṣẹ jọ fun alẹ kan ti o kun fun idunnu. Wọn gbe e lori ẹrọ amohunmaworan SuperSport ati DAZN, Bet9ja si ni olugbowo ere naa.
OJB News Yorùbá
