Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Katsina| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 13, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
*Iṣẹlẹ kayeefi kan ti ṣẹlẹ ni Ìpínlẹ̀ Katsina.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
Ikú tí pa gbajugbaja onkorin ni ìlànà Kristẹni, Ajinnrere G.A Aworinde lójú de
Ọmọ agbabọọlu Katsina United kan, Chinedu Ozor, ẹni ti wọn ti kede pe o ti kú lórí pápá ìṣeré, ni ó yá jì padà nínú mọ̀súárì.
Iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọsẹ yìí, lórí pápá ìṣeré Muhammadu Dikko Stadium to wa ni ilu Katsina, nígbà ti wọn n gba bọọlu ọrẹ́ pẹlu ikọ agbabọọlu Niger Tornadoes.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́rìí ṣe sọ, Ozor ṣubú lulẹ̀ lójijì lakoko ere naa, wọn si ni ọkàn rẹ ti dẹkun lilu, ti wọn si ti gbe e lọ si mọ̀súárì.
Ṣugbọn ninu iyalẹnu nla, o tun jí padà ninu mọ̀súárì, lẹsẹkẹsẹ ni wọn sá gbe e lọ si ilé-ìwòsàn nibi ti o ti n gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́.
Titi di asiko yii, awọn osise ile-iwosan ko ti sọ bi ara rẹ ṣe wa.
OJB News Yorùbá yoo tẹsiwaju lati fun yin ni iroyin siwaju si lori iṣẹlẹ naa.
