Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje 3, Oṣù Kẹjọ 2026.
Aárẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, kò kọ orúkọ ilé-ìwé prymaari àti secọndrì rẹ̀ sínú apá tí a yàn fún ẹ̀kọ́ nínú ìwé ìdánimọ̀ ara ẹni EC9 tí ó fi sílẹ̀ fún Independent National Electoral Commission (INEC) fún ìdìbò ààrẹ ọdún 2027.
Nínú àwọn ìwé tí INEC tẹ jáde ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ìbámu pẹ̀lú àtẹ̀jọ́ tí wọ́n ṣe àtúnyẹ̀wò fún ètò ìdìbò gbogbogbòò 2027, àwọn ìwé yíyàn àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ àti igbá-kejì ààrẹ ni a rí.
Nígbà tí a wo fọ́ọ̀mù EC9 Tinubu, a rí i pé ààrẹ náà kọ B.Sc. nínú Business Administration tí ó gba ní Chicago State University ní ọdún 1979 nìkan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Àwọn apá tí a yàn fún ẹ̀kọ́ prymaari àti secọndrì rẹ̀ ni ó fi sílẹ̀ ní òfìfo.
Síbẹ̀, Tinubu so àwọn ẹ̀da ìwé-ẹ̀rí Yunifásítì rẹ̀ àti ti National Youth Service Corps (NYSC) mọ́ ìwé yíyàn rẹ̀.
Nínú fọ́ọ̀mù náà, ààrẹ náà sọ pé a bí i ní March 29, 1952 ní Èkó, ó sì sọ pé iṣẹ́ rẹ̀ ni “Olóṣèlú”. Ó tún sọ pé ó ṣiṣẹ́ ní Mobil Nigeria Limited láti 1983 sí 1992 kí ó tó di Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó láti 1999 sí 2007.
