ÌLÚ ILARO KÚN FỌFỌ́, Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LO Ń SUNKÚN BI WỌN ṢE SÌNKÚ OGOGO SILU ILARO

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aje 24, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Ìlú Ilaro, ni Ìjọba Ìbílẹ̀ Yewa South, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, kún fún omi ojú àti ìbànújẹ́ lónìí, ọjọ́ Ajé, August 24, 2026, bí wọn ṣe ṣe ìsìn ìkẹyìn fún akikanjú eré Yorùbá, Alhaji Taiwo Hassan, ẹni tí gbogbo ayé mọ̀ sí Ògogo.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Sẹ́nétọ̀ Olamilekan Adeola Yayi tí sọ̀rọ̀ ibanikedun lórí ikú Ogogo, gbajumo òní tíátà tó kú

Owo rèé, ikú rèé, ìyàwó l’anloodu fún mi ní faifu millionu kí n fún lóyún apá karùn-ún ìtàn akinkanju ọkùnrin kan nilu Sango-Ọta

Ògogo, ọmọ ọdún merindinlaadorin (66,) ni wọn sin ní ìlú abínibí rẹ̀ ní Ilaro gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Islam, lẹ́yìn tí ó jagun pẹ̀lú àrùn jẹjẹrẹ ìpele kẹrin (stage-four cancer) tí ó sì kú ní ọjọ́ Sundee, August 23, ni agogo mẹta ọ̀sán.

Alhaji Taiwo Hassan Babatunde Ogogo lọ sile ìkẹyìn

BÍ ISÌNKÙ ṢE LỌ:

Ókú rẹ̀ dé Ilaro ní ọjọ́ Sundee alẹ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì pèjọ ní Mọ́ṣáláṣí Àárín Ilaro (Ilaro Central Mosque) láti gba òkú rẹ̀ pẹ̀lú ìmọlẹ̀ ọkàn.

Janazah (àdúrà isìnkù) wáyé ní agogo 10:00 a.m. ní Asade Agunloye Pavilion Ground, gẹ́gẹ́ bí Olórí Imam Ilaro ṣe kéde.

Wọn tún ṣe ìdúró ìkẹyìn (laying-in-state) ní agogo 11:00 a.m. ní ibi kan náà.

Lẹ́yìn náà ni wọn gbe e lọ sí ibi ìsìnkù, wọn sì ṣe àdúrà Islam kí wọn tó sin in.

 

Ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀: Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn Dapo Abiodun, Mr Latin (Bolaji Amusan) olórí TAMPAN, Yinka Quadri, Jide Kosoko, Toyosi Adesanya àti àwọn òṣèré mìíràn.

Yinka Quadri sọkun gidigidi nígbà tí wọn ń sin Ògogo, KWAM1 náà sọkun lórí ìtàgé ní Mushin nígbà tí ó gbọ́ ikú rẹ̀.

Alhaji Taiwo Hassan Ogogo ṣáájú kí Ọlọjọ tó dé

Ẹ̀KÚN ỌKÀN:

Ògogo bẹ̀rẹ̀ eré ní 1981 gẹ́gẹ́ bí mékánìkì, ó sì fi iṣẹ́ Water Corporation sílẹ̀ ní 1994 láti ṣe eré ní kikún. Ó di gbajúmọ̀ pẹ̀lú eré Owo Blow.

 

Ààrẹ Tinubu, Sẹnatọ Yayi (Solomon Adeola), àti ọ̀pọ̀ òṣèré bíi Femi Adebayo, Saidi Balogun, Toyin Adewale gbogbo wọn sọ ọ̀rọ̀ ìkẹdùn.

Ògogo ti lọ, ṣùgbọ́n orúkọ rẹ̀ yóò wà títí láé.

Sun re o, Ogogo Ilaro! O ṣe rere, o gbóríyìn!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.