Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 6, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu Naijiria (NAF) ti gbé orukọ awọn eniyan marundinlọgbọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu NAF 931 ti o ja ni agbegbe Igbokoda, ni Ipinlẹ Ondo sita.
Gẹgẹ bi atẹjade ti NAF fi sita, awọn eniyan 25 ni o wa ninu baluu naa – awọn awakọ ati oṣiṣẹ marun-un ati awọn ero ogun.

Baluu naa wa lori iṣẹ deede lati Benin lọ si Eko nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ. Titi di bayi, a ko ri ẹnikẹni ti o ye ninu wọn.

Ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu sọ pe iwadi kikun ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba naa.
Wọn si rọ gbogbo ara ilu lati yago fun arosọ ati kaakiri iroyin ti a ko fidi mulẹ, ki wọn si bọwọ fun aṣiri ati iyi awọn idile ti ajalu naa kan.

ÀWỌN TÓ KÚ NÍNU ÌJÀMBA NÁÀ:
ÀWỌN AWAKỌ̀ ÀTI OṢIṢẸ́ BÀLÚÙ (CREW – 5)
Squadron Leader MI Aburime — Flight Captain (Olori Awakọ)
Squadron Leader AP Man-Ugwueje — Co-pilot
Flight Lieutenant IS Bako — Co-pilot
Warrant Officer Abubakar A — Aircraft Technician
Corporal Uguru HC — Aircraft Technician

ÀWỌN ERO INU BÀLÚÙ (PASSENGERS – 20)
Flight Lieutenant TL Lazarus
Flight Lieutenant M Akinloye
Flying Officer IM Adeshina
Master Warrant Officer Onwuka F
Master Warrant Officer Matini BA
Warrant Officer Nuhu FS

Flight Sergeant James RB
Flight Sergeant Mohammed AI
Sergeant Ani AE
Sergeant Izibenikien SI
Sergeant Alafuka C

Sergeant Mbadugha AN
Lance Corporal Ugwuba FC
Lance Corporal Eledan GE
Mrs Ezeh Nneka
Godstmine Tarabina
Joy Micheal
Sunday Micheal
Ukeme David
Gideon Omotola

Ile-iṣẹ NAF fi ikẹdun rẹ ranṣẹ si awọn idile, awọn ọrẹ ati awọn akẹgbẹ iṣẹ gbogbo awọn ti o ku ninu ajalu ọjọ Aje naa.
Ki ọkàn gbogbo awọn to papoda maa ba Ọlọrun gbe. Ki Ọlọrun fun awọn idile wọn ni okun lati gba adanu nla yi.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
OJB News Yorùbá yoo tẹsiwaju lati mu iroyin kẹkẹẹ wa fun yin bi iwadi ba n tẹsiwaju.

One thought on “ILE ISẸ ỌMỌ OLÒGÚN GBÉ ORÚKỌ ÀWỌN MEEDOGBON TOKU NÍNÚ BAALU NAF 931 NILU IGBỌKỌ́DA”