Orísun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Bolanle Rasaq, Èkìtì | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aje, 27, Osu Keje 2026.
Ayo ti kun okan gbogbo omo ipinle Ekiti bi Ile-Ejo Giga julọ ni Naijiria ṣe fi edidi re le ibo Aare Biodun Abayomi Oyebanji gege bi Gomina tootọ ti ipinle Ekiti.
Idajọ naa ti pari gbogbo ariyanjiyan ati ẹjọ ti o tẹle eto idibo to kọja.
Ni ihin ayo rẹ lẹhin idajọ naa, Iyawo Gomina Eko tẹlẹri, iyaafin to ni ọkan rere fun idagbasoke, ti ki Gomina Oyebanji ku oriire, o si so pe idajọ naa jẹ ododo ati ifẹ Ọlọrun fun awọn ara Ekiti.
O ni, “Idajọ Ile-Ejo Giga yii kii ṣe fun Oyebanji nikan, fun gbogbo ọmọ Ekiti ni. Eyi ni akoko lati gbe gbogbo ija sile, ki a si parapo.”
O rọ gbogbo awọn oloselu, boya ẹgbẹ kan tabi ekeji, ati gbogbo ọmọ Ekiti, ka wa papọ lati ṣe atilẹyin fun ijọba Oyebanji, nitori ninu iṣọkan ati alafia nikan ni idagbasoke gidi ti le waye.
Bayi ni tẹle ń tẹle, ọna ti ṣí silẹ fun Gomina Oyebanji lati tẹsiwaju ninu iṣẹ rere ti o ti bẹrẹ fun ilẹ Ekiti.
