Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Lekan Lawal, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku 31, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Agbẹjọro Ààrẹ Bola Tinubu ní America, Wole Afolabi, SAN, ti ṣàlàyé ìdí tí America kò fi mú Tinubu lẹ́yìn ẹ̀sùn gbigbé oògùn líle àti nípa àwọn ẹjọ́ mìíràn lórí ifọrọwerọ pẹlu rẹ lórí ètò Sunday Politics.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ọrọ b’ẹyin yọ bí àwọn òṣèlú alátakò ṣe lu’lẹ̀ níbi ìpàdé wọn nilu Abújá lọjọ ajé…
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Oloye Olusegun Obasanjo sọ pé kò tíì sí ìjọba àwa a rawa ni gbogbo ilẹ̀ Afrika bayi…
Kí ni Afolabi sọ lórí Channels TV Sunday Politics?
Ó sọ pé bí ẹ̀rí tó péye bá wà, America ìbá ti fi ẹ̀sùn kan Tinubu, ìbá ti mú un, ìbá ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
“Kinni òun to dá yàtọ̀ nípa Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu láti máa lé wa si Amerika tàbí fi fi Amẹ́ríkà silẹ lai jẹ́ pé wọn fọwọ́ òfin mú, di dá dúró, fifi ọrọ wá lẹ́nu wò fún òun kò’un” eyii ni ọrọ ti Wole Afolabi bèèrè.
Ó fi àpẹẹrẹ àwọn olórí bíi Manuel Noriega ti Panama tí America mú lọ sí US, Andrew Fahie ti British Virgin Islands tí a mú ní April 2022, àti àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n ti kó lọ sí US fún ẹ̀sùn oògùn, pé America kì í ṣàánú ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rí bá wà.

Ẹ̀sùn owó $460,000:
Ó sọ pé $460,000 tí Tinubu forfeited ní 1993 jẹ́ civil forfeiture, kì í ṣe criminal conviction. Bí ó bá jẹ́ ẹlẹ́bi, wọn ìbá ti fi ẹ̀sùn kan án.
Nígbà tí wọ́n bi í léèrè bóyá Tinubu kò tíì mu oògùn rí, kò tíì mú heroin rí, kò sì tíì ṣe olùgbé oògùn, ó dáhùn:
“Ohun tí ẹ̀rí fi hàn ni mo gbẹ́kẹ̀ lé”.
Ìjà Ofin FOIA:
Àríyànjiyàn wà lórí ẹjọ́ FOIA tí Aaron Greenspan fi sílẹ̀ láti gba àwọn ìwé FBI, DEA àti DOJ. Ẹgbẹ́ẹgbẹ̀rún ojú-èwé ti jáde, ṣùgbọ́n 399 ojú-èwé kan ṣoṣo ni wọ́n ṣì ń díjẹ. Afolabi sọ pé FBI fẹ́ dáàbò bo àwọn agents, orísun ìròyìn àti ọ̀nà ìwádìí wọn, kì í ṣe Tinubu.
Nínú filing kan ní ojú-èwé 24, DOJ sọ pé ìdààmú wọn ni methodology, kò sí ìdáàbòbò fún Tinubu.
Ó sọ pé ẹjọ́ náà jẹ́ ẹ̀tọ́ òfin, kì í ṣe láti fi ẹ̀rí pamọ́.

One thought on “ÌDÍ RÈÉ TÍ ORILẸ-EDE AMẸRIKA Ó FI LÈ GBÉ TINUBU – Wole Afolabi”