Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Iṣẹgun, 3, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ileeṣẹ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti dá sí ọ̀rọ̀ ìjàngbà tó wà láàrín ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ olórin ìjọsìn tó gbajúmọ̀ nni, Olayemi Bolaji tí a mọ̀ sí Toluwanisings, lẹ́yìn ariyanjiyan lórí ètò ìbòjì rẹ̀.
Ileeṣẹ ọlọ́pàá sọ pé àwọn igun méjèèjì náà fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà ní ọjọ́ Ìsẹ́gun, November 3, 2026, ní olú ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ní Eleyele, Ibadan, lẹ́yìn tí Kọmísánà ọlọ́pàá, Abimbola Olugbenga, pe wọn.

KÍNI Ó FA ÌDÁWỌ́LÉ ỌLỌ́PÀÁ?
Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ ọlọ́pàá, Ayanlade Olayinka ṣe sọ nínú àtẹ̀jáde tí ó fọwọ́ sí:
Kọmísánà gba ìròyìn ní October 28 nípa ìyapa tó wà láàrín ìdílé olórin náà àti àwọn ọrẹ́ rẹ̀ lórí ètò ìbòjì. Nítorí pé ọ̀rọ̀ náà lè fa ìdàrú àlàáfíà, ó lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Abala 4 ti Òfin Ọlọ́pàá láti pe gbogbo ẹgbẹ́ wá fún ìpàdé láti dènà kí ọ̀rọ̀ náà má ba burú sí i.
Ìpàdé náà wáyé nítorí ẹ̀sùn bíi ìdìtẹ, ẹ̀sùn èké lórí ìwà, àti ìwà tó lè fa ìdàrú àlàáfíà tí ó ń wáyé lórí ayélujára nípa ikú àti ìbòjì olórin náà.
TANI TÓ FOWỌ́ SÍ ÀDÉHÙN NÁÀ?
*Àwọn tó fowọ́ sí àdéhùn àlàáfíà náà ni:
*Aya olóògbé: Olayemi Elizabeth Damilola
*Baba olóògbé: Muniru Olayemi
*Àwọn ọ̀rẹ́ àti alábàáṣiṣẹpọ̀: Oyindamola Esther, Babadunni Gbolabo àti Lawal Ademola Rafiu
Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ pàtàkì àti àwọn aṣojú mìíràn tún wà níbẹ̀.

KÍNI ÀDÉHÙN NÁÀ SỌ?
Gẹ́gẹ́ bí ọlọ́pàá ṣe sọ:
“Àwọn igun méjèèjì gba láti máa wà ní àlàáfíà àti láti huwa rere, kí wọn má ṣe ohun tó lè fa ìdàrú daapọ àlàáfíà, kí wọn sì dáwọ́ dúró kíkó ìròyìn lórí ayélujára, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo àti ọ̀rọ̀ tó lè mú kí ìjàngbà náà burú sí i.”
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Àdéhùn náà tún sọ pé:
Kí wọn má ṣe máa tàn ìròyìn, ẹ̀sùn àti àtẹ̀jáde nípa ọ̀rọ̀ náà lórí Facebook, Instagram, ìwé ìròyìn, rédíò, bulọọgi àti ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ mìíràn.
Kí àwọn aṣoju wọn, àwọn alábàáṣiṣẹpọ̀ àti ẹni tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún má ṣe ṣe, ṣe àtìlẹ́yìn, tàbí tànkálẹ̀ àtẹ̀jáde tó lè tún fa ìjàngbà náà.
Kọmísánà kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá rú àdéhùn náà, tàbí tó bá lo àyípadà ikú olórin náà láti dá ìja sílẹ̀, tàbí láti máa tàn ẹ̀sùn tí kò ní ẹ̀rí, ni wọn yóò mú tí wọn yóò sì ṣe lẹ́jọ́.
Ó tún bẹ àwọn ará ìlú, àwọn blogger àti àwọn oníròyìn láti ṣọ́ra, kí wọn má ṣe máa tàn ìròyìn tí a kò tíì jẹ́rìí tó lè tún fa wahala.

ÌDÍ TÍ ÌJÀNGBÀ NÁÀ ṢE BẸ̀RẸ̀
Ìjàngbà náà dá lórí ibi tí wọ́n yóò sin Toluwanisings sí.
Baba rẹ̀ fẹ́ kí wọ́n sin ín sílé tí ó kọ́ ní Adegbayi, Egbeda, tàbí lẹ́gbẹ̀ẹ́ iya rẹ̀ tó ti kú ní Ìpínlẹ̀ Osun, nígbà tí aya rẹ̀ kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n sin ín sínú ilé tí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ń gbé.

ÌRÒYÌN TÓ WÀ NÍ Ẹ̀YÌN RẸ̀
Toluwanisings kú ní Ibadan ní October 14, 2026, lẹ́yìn tí ó ṣubú lójijì. Ikú rẹ̀ fa ariwo nítorí ẹ̀sùn pé wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn bíi méje tàbí méjọ ṣùgbọ́n wọn kọ̀ láti gba á, nígbà tí Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ Babadunni Gbolabo sọ bẹ́ẹ̀. UCH, Ibadan sọ pé kò sí àkọsílẹ̀ pé wọ́n mú un wá síbẹ̀.
Ní báyìí, pẹ̀lú àdéhùn àlàáfíà tí ọlọ́pàá ṣe, a retí pé ìbòjì olórin náà yóò wáyé láìsí wahala.
OJB News Yorùbá yóò tẹ̀síwájú láti fún yín ní ìròyìn tó péye lórí ọ̀rọ̀ yìí.

One thought on “Ibojì Toluwanisings: ÀWỌN ẸBÍ ÀTI AYA RẸ T’ỌWỌ BỌ̀’WE ÀDÉHÙN ÀLÀÁFÍÀ PẸ̀LÚ ILEEṢẸ ỌLỌPA”