Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Sango-Ọta| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje 17, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin Yorùbá, Tola Oladokun, ti ṣí ohun ìbànújẹ́ tó wà lọ́kàn rẹ̀ síta lórí ìdí tí òun àti gbajúmọ̀ òṣèré, Taiwo Hassan Ogogo fi yapa.
Gẹ́gẹ́ bí Tola ṣe sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tuntun kan, Ogogo ti pe òun nígbà kan rí fún eré rẹ̀ tó gbajúmọ̀ “Iya Ibeji Eleran Igbe”, níbi tí ó fẹ́ kí Tola ṣe olú-ẹ̀dá ìtàn náà nítorí pé ipa náà nílò ẹni tí ó ní ilà lójú.
Tola sọ pé Ogogo tilẹ̀ kò owó púpọ̀ fun un, ṣùgbọ́n ní àkókò náà, ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un pé kó dáwọ́ eré ṣíṣe dúró. Nítorí ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀, Tola kọ̀ láti gba ipa náà.
Lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ náà, Ogogo lọ bá àgbà òṣèré nnì, Iya Ngba Life (aláìsí) tí kò ní ilà, wọ́n sì ṣe ilà oníṣẹ́-ọnà fún un lójú fún eré náà.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
El-Rufai ti wọ àjọ ICPC lọ sile ẹjọ́ òní kí wọn ba òun gba 10 Billionu lọ́wọ́ wọn..
Tola sọ pé:
“Ogogo bàjẹ́ gidigidi nítorí pé mo kọ̀ ipa náà. Láti ọjọ́ náà lọ, kò tún pe mí mọ́ fún eré rẹ̀ kan rárá. Èyí dùn mí gan-an.”
Ìtàn yìí ti mú ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ayélujára. Àwọn kan sọ pé ó yẹ kí ó bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, àwọn mìíràn sọ pé ó pàdánù àǹfààní ńlá tó lè yí ìgbésí ayé eré rẹ̀ padà.
Ẹ̀yin olólùfẹ́ OJB News Yoruba, ṣé Tola ṣe àṣeyọrí nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ tàbí ó yẹ kí ó ti gba àǹfààní náà? Ẹ sọ èrò yín nínú comment.
