Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 8, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ọ̀kan lára àwọn òbí àwọn agunbanirọ ogún tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ajínigbé ní ìpínlẹ̀ Ímò ti ṣàlàyé fún oniroyin pé àwọn òbí náà fúnra wọn ni wọ́n san owó dọ́là fún àwọn ajínigbé kí wọ́n tó tú àwọn ọmọ wọn sílẹ̀.
Òbí náà tí kò fẹ́ kí a darúkọ orúkọ rẹ̀ fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé:
“Ẹnikẹ́ni kọ́ lo ṣokùnfà bí wọ́n ṣe gba àwọn ọmọ wa sílẹ̀. Àwọn òbí àti àwọn èèyàn lórí ayélujára pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa ló da owó jọ fún òbí kọọkan láti san owó tí àwọn ajínigbé béèrè fún.

Ìjọba ò san owó kankan fún ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ wa, kò sì sí nǹkan tó jọ mọ́ pé ìjọba tàbí àwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ààbò dóla àwọn ọmọ wa.
Owó náà sì pọ̀ gan-an, kì í ṣe owó kékeré.”
Ó tún ṣàlàyé pé àjọ ọtẹlẹmu yẹ DSS mọ nípa bí wọ́n ṣe ṣe owó náà sí dọ́là lọ́wọ́ àwọn Aboki kí wọ́n tó kó owó náà lọ fún àwọn ajínigbé. Ó ní DSS pàápàá ránṣẹ́ pe àwọn òbí pé kí wọ́n wá láti lè ràn iṣẹ́ ìwádìí wọn lọ́wọ́.

Òbí náà kọ̀ láti sọ iye owó dọ́là tí wọ́n san, ṣùgbọ́n ó sọ pé ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ mọ́ lórí kí ọmọ rẹ̀ máa ṣe ìsìnrúùlù ní Ímò.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Eyii ni òun ti a mọ nípa bí àwọn agunbaniro tí wọn jì gbé ṣe rí òmìnira gba báyìí….
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ:
“Ọmọ mi kò ní ṣe ìsìnrúùlù mọ́ ní Ímò. Mo fẹ́ kí àjọ NYSC fún un láàyè láti padà sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tàbí ìpínlẹ̀ Ògùn láti wá ṣe ìsìnrúùlù rẹ̀. Tí NYSC kò bá gbà á láàyè, kò ní ṣe ìsìnrúùlù mọ́.”
Ẹ̀yìn rẹ̀, ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ elétò ààbò mìíràn ló dóla àwọn agunbanirọ náà, àti pé iṣẹ́ ń lọ láti fọwọ́ ṣinkùn àwọn ajínigbé náà.
Ìròyìn yìí ń tẹ̀síwájú láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ ààbò àwọn agunbanirọ ní orílẹ̀-èdè yìí ṣì ń jẹ́ àníyàn ńlá fún àwọn òbí.

One thought on “Ẹ wá gbọ́ túntún! IJỌBA Ó MỌ NÍPA BI A ṢE GBA ÀWỌN ỌMỌ WÁ JÁDE, KO SÍ ẸSỌ ALA’ABO KÀN, OWO LAFI GBA WỌN KALẸ”