Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 29, Oṣù Keje 2026.
Gbogbo ilẹ̀ ń rọ lọ́wọ́ lórí ìjà tó wáyé lálẹ́ ana, ọjọ́ 31st July tí ó wọ August 1st, ní Balmoral Hall, Federal Palace Hotel, Victoria Island, Eko.
Wọ́n pe ìjà náà ní “UNFINISHED BUSINESS” – Chaos in the Ring 4. Ìjà méjì pàtàkì ló wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n ti Portable àti Charles Okocha tí gbogbo ojú fẹ́ wo.
BÁWO NÍ ÌJÀ NÁÀ ṢE BẸ̀RẸ̀?
Tí ìjà náà bá jẹ́ boxing gidi, kò pẹ́ ju iṣẹ́jú kan lọ. Portable tí ó wọ ṣòkòtò aláwọ̀ buluu àti funfun, àti Charles tí ó wọ ti pupa, bẹ̀rẹ̀. Kíákíá, Portable pa eré boxing tì, ó yí i padà sí gbajúmọ́.
Ó gbá Charles gbangba, ó gbé e sókè, ó jù ú lulẹ̀, ó sì tẹ ẹ́ mọ́lẹ̀ bí àwọn tó ń ṣe WWE. Referee, obìnrin kan, ń pariwo, ń gbìyànjú láti yà wọ́n, ṣùgbọ́n Portable kò gbọ́.
OHUN TÓ MÚ KÍ WỌ́N DÁ ÌJÀ NÁÀ DÚRÓ
Láìròtẹ́lẹ̀, Portable fò jáde kúrò nínú ringi. Ó sáré lọ sí àárín àwọn ènìyàn, ó ń náwọ́ lé ẹnìkan, lẹ́yìn náà ó sá lọ pátápátá kúrò níbi iṣẹ́lẹ̀ náà. Ó kọ̀ láti padà wá fún round keji.
Nítorí ìwà yìí, àwọn adájọ́ kéde pé Portable ti jẹ disqualify. Wọ́n gbé ọwọ́ Charles Okocha sókè gẹ́gẹ́ bí olùborí pẹ̀lú TKO, wọ́n sì dè bẹ́ẹ̀tì lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ẹ̀SÙN “Ó JẸ MI LẸ́YÌN “
Lẹ́yìn náà ni drama tòótọ́ bẹ̀rẹ̀.
Portable ṣe video ní òru, aṣọ kò sí lọ́rùn rẹ̀, irun funfun, ó ń pariwo. Ó ní Charles jẹ ẹ́ ní ẹ̀yìn. Ó yí ẹ̀yìn rẹ̀ padà, ó fi àmì pupa kékeré kan hàn, ó ní Charles tó wọ mouth guard nínú ẹnu rẹ̀ ló jẹ ẹ́.
Ọ̀rọ̀ yìí ló mú kí internet rú. Ọ̀pọ̀ ènìyàn lórí Instagram àti Facebook ń rẹ́rìn-ín, wọ́n ń sọ pé:
“Báwo ni ẹni tó wọ irin ààbò ẹnu ṣe lè jẹ ọ?”
“Portable sá nítorí ó bẹ̀rù, kì í ṣe nítorí jíjẹni”
“Èyí kì í ṣe boxing mọ́, Gidigbo ni”
Àlàáfíà kò sí láàrín méjèèjì rárá. Ìjà àkọ́kọ́ ní ọdún 2023 náà ni Portable borí, ṣùgbọ́n Charles sọ pé ojoro ni. Bayi Charles ti san ẹ̀san padà.
Ní báyìí, Charles ń sọ pé òun fẹ́ bá Carter Efe jà, ẹni tó borí Portable ní ìgbà tó kọjá, nígbà tí Portable ń sọ pé òun kò gba àbájáde yìí.
