Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ
Ijoba Ipinle Osun ti gbe igbese ńlá kàn tí ó ṣe ṣe kí ó mú kí wọn ó padà rọ Oluwo tilu Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi lóye, kí wọn ó jawe lọ rọkun nile fún Ọba naa, kò sì òun méjì tí ó fà eyii ju bí Ọba náà ṣe ń sọ̀rọ̀ sakasaka sì àwọn Ọba àlàyé àti ti tàbùkù bá àwọn ẹṣin kàn tó fi mọ fífi àṣà at’ise ìran Yorùbá tó jọba lé lórí wọlẹ láwùjọ.
Ijọba ipinlẹ Ọṣun kò sai menuba pé isesi Oluwo kò mú ìdùnnú bá ìjọba ipinlẹ náà, eyii mú Ọba náà wá ní abẹ akiyesi to jinle lori awon oro e lenu ti won pe ni ohun ti o le fa ija esin ati ija ilu-si-ilu.
Ninu leta ikilo kan ti o jade lati ọ́fíìsì Akowe Agba, Ministry of Local Government and Chieftaincy Affairs, ti o ni nomba itokasi CD.17/1/VOL.VIII/377, ti wọn fi lédè ni ọjọ kẹrin oṣù kọkànlá 2026, ti Wale Alliyu si fọwọ́ sì fun Akowe Agba, ijoba pàṣẹ fun Oluwo lati dawoduro lati ma ba eniyan ti o ni igbagbo miran wi, ati lati ma ba awon Oba alayeje wi jọ.
Ọba Rasheed Akanbi oluwo ìlú iwo
Eda leta naa kan, ti The PUNCH rí gbà ni Osogbo ni ojo Wednesday, ni a tun fi ranse si Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, gege bi Alaga Igbimo awon Ọba ni Ipinle Osun.
KÍNNÍ ÌJỌBA SỌ NÍNÚ LẸ́TÀ NA?
Ijoba fi esun kan Oluwo pe ise ati ọrọ rẹ n gbe wahala soke, o n gbin irugbin ija esin ati ija ilu, o si n ba oruko ati asa ile Yoruba je.
Ijoba so pe:
“O ko le sọ̀rọ̀ jù, o si gbọdọ ma huwa ni ọna ti o le fa rògbòdìyàn esin nipa sísọ ọrọ búburú lu eniyan ti o ni igbagbo miran. Ìtẹ́ Ọba ko gbọdọ jẹ ohun ti a fi n fa ogun tàbí ìjà esin, awon ti o wa lori re gbọ́dọ̀ si ma ranti lati ma ba asa ati ise ilu ti won n dari je.”
Ijoba tun so pe àwọn ti wo awon ọ̀rọ̀ ati fidio ti Ọba Akanbi n gbejade leyi tó kún fún àtakò, pe o ya wọn lẹ́nu gidigidi.
Ẹda ìwé tí ìjọba ipinlẹ Ọṣun kò
Eyii ni awon Ofin Ikiloo Meefa ti Ijoba pa lase ni:
*Ki Oba dawoduro lori ikolu si eniyan ti o ni igbagbo miran – gbogbo ọmọ ilu ni ẹtọ si ominira ẹṣin.
*Ki o dawoduro lati ma ba awon Oba alayeje wi lati dena ija ilu-si-ilu.
*Ki o sise lati daabo bo asa ati ise ilu ti ìtẹ́ ti o wa lori rẹ duro fun.
*Ki o tẹle ofin ati ilana ihuwasi ti o wa ninu Chieftaincy Laws ati ipinnu Ìgbìmọ̀ awon Ọba.
Abala kejì ìwé tí ìjọba ipinlẹ Ọṣun kò sì Oluwo
Ile-ise Ministry of Local Government and Chieftaincy Affairs yoo ma boju to ìwọ̀nba àkókò ti Ọba bá fi tele awon ikilọ naa.
A pàṣẹ fun Igbimo awon Ọba ti Ipinle Ọṣun (State Council of Obas) lati maa boju to ati lati ṣiṣẹ lori ohun ti n ṣẹlẹ̀ ni Iwo.
Ijọba kò sai tun tẹ mọ Ọba leti pe ipa Ọba gidi ni lati daabo bo asa ilu, kii se lati se atunse ti o le fa ìwà-ipá ni awujo.
Oluwo ọba Rasheed Akanbi àti yeye ọba
IWADI JINLE OJB NEWS YORÙBÁ: Kí ní o fa Lẹ́tà yi?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé leta naa ko dárúkọ ọrọ kan pato, iwadi wa fihan pe Oluwo ti n lo oju opo Facebook rẹ jù lati fi ẹ̀sùn kan àwọn Ọba Yoruba miran pe wọn n se ise orisa.
Oluwo tilu Iwo láàfin rẹ
Gege bi ìwádìí wá ṣe fìdí ẹ múlẹ̀:
Ni July 1, 2026: Ninu fidio kan ti o gbe sori Facebook re, Oba Akanbi so pe ise ayẹwo lati fi Ọba tuntun jẹ ise igbekun (traditional rites and seclusion) ki se ohun ti o dara, o ni ona lati ko awon Ọba sinu iru ẹbọ ni.
Ni October 10, 2026: Ninu fidio miran, o sọ pe ero ade àtijọ́ (ancient crown) jẹ́ ẹtan lasan, pe ade ni awon Oba ti o wo o lo n se.
Eyi kii se igba akoko. Lati igba ti Oba Akanbi gori ite ni 2016, o ti gbe ipinnu akoko re gege bi ija si ijosin orisa ni afin, o so pe orisa yẹ ki o wa ni musiuamu, kii se ni afin. Oro yi ti mu ariwo nla laarin awon oniseese ati awon Oba àlàyé, ti o si ti mu ki won pe e ni Oba ti o n tako asa Yoruba.
Ọba Rasheed Akanbi oluwo ìlú iwo
Ipo Ofin ati Isegun?
Ofin Ilana Naijiria fun gbogbo omo ilu ni ominira lati yan ẹṣin. Ijoba Ọṣun lè fi Oluwo jẹ gẹ́gẹ́ bi Oba, o di dandan fun un lati bọ̀wọ̀ fun eto yi.
Amoye eto ijoba ibile ni Osun so fun OJB News Yoruba pe, igbese yi tumo si pe:
Ti Oluwo ba tun se bẹẹ, Ìgbìmọ̀ Ọba le gbe igbese ibawi siwaju si, pelu gbigbe ọrọ rẹ lọ síwájú Gomina.
Ileeṣẹ ijọba ìbílẹ̀ to n ri sì ọrọ òye àti ọba jíjẹ le pe e fun alaye (query) tabi da igbese yíyọ nípò tàbí dá dúró fún ìgbà kan (suspension) ti o ba rufu ofin Chieftaincy.
Fífi ránṣẹ́ ẹ̀dá lẹ́tà si Ooni túmọ̀ si pe ìjọba fẹ́ lo agbara ati ọla Ìgbìmọ̀ àjọ lọbalọba lati dena wahala ki o to ru soke.
Oba Rasheed Akanbi oluwo ìlú iwo
Esi Lati Afin Oluwo
Nigba ti a kan si Akowe irohin Oluwo, Alli Ibraheem, lori ero-ibanisoro, o so pe Ọba ko ti gba leta kankan lati ọdọ ìjọba ipinlẹ Ọṣun.
Síbẹ̀, àwọn oluwoye ọrọ oselu ni Ipinlẹ Ọṣun ro pe ìjọba ti de opin suuru rẹ lori awon ọ̀rọ̀ ti o n fa ariwo lori ayelujara, paapaa ni akoko ti ipinlẹ Ọṣun n gbiyanju lati mu alaafia ati iduro isinpo ẹṣin duro.
OJB News Yoruba yoo ma tẹ̀síwájú lati boju to ọrọ yi, ti a o si kan si Ìgbìmọ̀ àwọn lọbalọba fun esi wọn.
One thought on “BI OLUWO Ó BÁ SỌRA Ẹ, AFAIMO NI KI IJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ỌṢUN Ó MA YỌ DÀNÙ”
One thought on “BI OLUWO Ó BÁ SỌRA Ẹ, AFAIMO NI KI IJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ỌṢUN Ó MA YỌ DÀNÙ”