Mustapha Sego, alaga egbe onimoto NURTW ipinle Eko

ÈYÍI NÌ ÌDÍ TÍ ADAJỌ FI NI KI WỌN Ò LỌ GBÉ MUSTAPHA SEGO PAMỌ S’OGBA Ẹ̀WỌ̀N

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Iṣẹgun, 13, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Lànà òde yìí ni ile ẹjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ pàṣẹ fún àwọn agbófinró láti wá gbogbo ọna láti gbé alága ẹgbẹ́ àwọn onimoto ni ipinlẹ Èkó, Mustapha Adekunle Sego àti enikeji rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń béèrè pé kinni ìdí tí ilé ẹjọ́ fi ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n eyii ni eredi gbìgbé Sego lọ sọ́gbà ẹwọ̀n Kirikiri.

 

 

Mustapha Adekunle Sego alaga NURTW ipinlẹ Èkó

 

ÌDÍ TÍ ILÉ-ẸJỌ FI PÀṢẸ KÍ WỌN MÚ ALÁGA NURTW ÈKÓ ÀTI AKỌ̀WÉ RẸ̀ 

Iwadi OJB News fihan pe wahala naa ko bere loni. O bere lati igba ti Egbe awon Onikeke Maruwa, ti won n pe ni Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN) lo lọ si ile-ejo.

 

Ni ojo 11th December, 2025, Ile-ejo Awon Osise ti pase pe TOAN je egbe ominira ti o ni eto lati sise lori ara re, ti NURTW ko gbodo ma gba owo Ticket lojoojumo, ti ose kan, ati ti aabo (security ticket) lowo awon onikeke Maruwa mo.

 

Sugbon TOAN fẹsùn kan pe pelu idajo naa, awon omo egbe NURTW ti Sego n dari si n tesiwaju lati gba owo naa, ti won si n halẹ mọ awon omo egbe won ni awon paki bi ni Oshodi, Mile 2, Iyana Ipaja, ati Berger.

 

Eyi lo mu ki TOAN tun pada lo si ile-ejo lati fi ejo aigboran (contempt proceedings) kan Sego ati Usman Teslim.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Kínní òfin orile-ede Naijiria sọ nípa sìn sìn òkú sínú ilé’gbe tí ẹnì náà fowo ara rẹ kó. *kinni òfin sọ lórí a ń sìn òkú sínú ile’gbé…..

Ṣé lóòótọ́ nipe àwọn Ọlọpa kò èèyàn mokanla to jẹ afurasi nínú ìkọlù tí wọn ṣe sí gbajugbaja ajafeto ọmọniyan Omoyele Sowore at’awon eeyan rẹ, èyí ni okodoro ọrọ naa. *O ni ìkọlù náà lọ́wọ́ òṣèlú nínú..

 

Onidajo Binusoke Lori Aigboran:

Ni ojo Aje, November 2, 2026, Onidajo Isaac Essien pa ase naa lẹhin ti Sego ati Teslim ko yoju niwaju ile-ejo lati se alaye idi ti a ko fi gbodo ran won lewon.

 

Onidajo ni iwa won je aigboran to ga ju, ati pe won n fi agbara ile-ejo se yẹyẹ.

Polówó ọjà tàbí kí o ṣe ìkéde rẹ pẹlu wá lórí ìkan OJB MEDIAS HUB, pé ẹ̀rọ ibanisoro yíi +2348066952410

Onidajo tun binu gidigidi lori iwe affidavit ti Bailiff ile-ejo kan, Ayo Moses, kọ. O ni ni October 5, 2026, Oga awon Oluso (Chief Security Officer) fun eni kan ninu awon ti won ni lati sanwo idajo naa da oun duro, ko si je ki oun te iwe ile-ejo. Onidajo pe eyi je ewu nla fun eto idajo.

 

Ase Ti Ile-ejo Pa Tuntun:

Ki Komisona Olopa Ipinle Eko, Akoso NSCDC Ipinle Eko, ati gbogbo awon agbofinro miran mu Sego ati Teslim lona jiju.

Ki won ju won si Ile-ewon Kirikiri ki won duro sibe titi ti won o fi yoju lati nu ara won ninu ejo aigboran naa.

Ejo naa ti sun siwaju titi di ojo November 16, 2026.

 

Ohun Ti o Sele Bayi:

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni owurọ ọjọ Iṣẹgun, Tuesday, awọn ọlọpaa ni wọn tun n duro de iwe aṣẹ ti o pe (Certified True Copy) lati ile-ẹjọ, ati pe titi di isinsinyi, Alhaji Sego ko ti yoju, foonu rẹ paapaa ti pa.

 

Ija laarin NURTW ati TOAN lori gbigba owo ticket ni Eko ti pẹ to. Idajo tuntun yii yoo pinnu boya awọn ẹgbẹ ọkọ yoo bọwọ fun ofin tabi bẹẹkọ.

 

OJB News Yoruba yoo maa fun yin ni imudojuiwọn.

One thought on “ÈYÍI NÌ ÌDÍ TÍ ADAJỌ FI NI KI WỌN Ò LỌ GBÉ MUSTAPHA SEGO PAMỌ S’OGBA Ẹ̀WỌ̀N”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.