Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje, 2, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ìjà ńlá ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú apá kan àwọn ìdílé ní Nàìjíríà ní ọdún 2026 yìí. Èrò ìdílé náà ni bóyá kí wọn sin ọmọ wọn tí ó kú sínú mansion àgbà tí òun fúnra rẹ̀ kọ́, tàbí kí wọn lọ sin ín sí ilẹ̀ ìsìnkú gbogbogbò.
Ọ̀rọ̀ náà ti di ariwo àti àlàáfíà kò sí mọ́ nínú ìdílé náà.
Ṣùgbọ́n ìbéèrè tí a gbọ́dọ̀ bi ni: Kí ló dé tí èyí fi ń di àríyànjiyàn?

OTÍTỌ́ NÍPA ÒFIN NÀÌJÍRÍÀ
Ìwádìí tí OJB News Yorùbá ṣe fihàn pé ọ̀rọ̀ òfin yìí kò ṣe tuntun rárá.
Nínú Section 246 ti Criminal Code Act Nàìjíríà, lábẹ́ Chapter 23 – Offences against Public Health, òfin sọ kedere pé:
Any person who without the consent of the President or the Governor buries or attempts to bury any corpse in any house, building premises, yard, garden, compound, or within a hundred yards of any dwelling-house, or in any open space situated within a township, is guilty of a misdemeanor and is liable to imprisonment for six months.
Ìtumọ̀ rẹ̀ ní Yorùbá:
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sin òkú tàbí gbìyànjú láti sin òkú sínú ilé, àwọn ilé, àgbàlá, ọgbà, tàbí láàrín ọgọ́rùn-ún yáàdì sí ilé gbígbé kan, tàbí ní ààyè gbangba tí ó wà nínú ìlú ńlá, láìsí àṣẹ Ààrẹ tàbí Gómìnà, ó ti ṣẹ̀, ẹ̀sùn misdemeanor ni, ó sì lè lọ sí ẹ̀wọ̀n fún oṣù mẹ́fà.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
KÍNI ÈYÍ TUMỌ̀ SÍ FÚN ÌDÍLÉ NÁÀ?
Níní Mansion kò túmọ̀ sí ẹ̀tọ́ ìsìnkú: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóògbé náà ló kọ́ mansion náà fúnra rẹ̀, tàbí ó ra ilẹ̀ náà, níní ilé kò fún ìdílé ní ẹ̀tọ́ òfin láti sin òkú síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ́kan.
Àṣẹ Gómìnà pàtàkì: Kí wọn tó lè sin òkú sí inú ilé tàbí àgbàlá ní Nàìjíríà, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà. Láìsí àṣẹ yìí, ìsìnkú náà jẹ́ ẹ̀sùn ọ̀daràn.
Kì í ṣe òfin tuntun: Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ti kílọ̀ fún àwọn ará ìlú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, bíi ní December 2013 àti ní ọdún 2020, pé wọn kọ̀ láti má sin òkú sí àgbàlá ilé, nítorí àrùn àti ìdàgbàsókè ìlú. Òfin náà sì sọ pé ẹnikẹ́ni tó fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ gba àṣẹ pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Gómìnà.

ÌKADIÌ FÚN ÀWỌN ÌDÍLÉ NÍ NÀÌJÍRÍÀ
Aṣa wa ni pé a fẹ́ràn láti sin àwọn olólùfẹ́ wa nítòsí wa, nítorí pé a gbàgbọ́ pé òkú àti ààyè wà pọ̀. Ṣùgbọ́n òfin orílẹ̀-èdè gbọ́dọ̀ bọ́wọ̀ fún.
Nítorí náà, kí ìjà ìdílé má ba pọ̀ si i, ohun tí ìdílé yìí nílò ni:
Kí wọn wá àṣẹ ìjọba (consent) kí wọn tó gbé ìgbésẹ̀ kankan.
Kí wọn mọ̀ pé tí wọn bá rú òfin yìí, ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà ló wà níbẹ̀.
Ilé tí ẹni kú kọ́ kì í di ilẹ̀ ìsìnkú lásán.
Ilé ńlá tí ọmọ náà kọ́ jẹ́ àmì ìtàn àti ìsapá rẹ̀, kì í ṣe ibi tí òfin gbà láti sọ di sáà.
OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀síwájú láti ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí.

One thought on “Kín l’ofin wí? Ń JẸ ÒFIN NÀÌJÍRÍÀ GBA LÁTI SÌNKÚ SÍNÚ ILÉ TO KỌ FÚN RA’RẸ”