NIBO LEYIN N GBE, NIBO LEYIN WA NIGBA TI ÀÀRẸ BỌLA AHMED TINUBU SUN ṢẸẸ̀LI ỌLỌPA L’AYE SANNI ABACHA

Orísun: OJB News Yoruba | O’nkotan: Lekan Lawal, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 1, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Nibo lẹ́yìn ń gbé, nibo lẹ́yìn wá nígbà tí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu at’awon meedogbon mìíràn fojú wí iná ni ago ọlọpaa nilu Èkó yìí, bóyá lẹ mọ̀ pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti wà nínú sẹ́ẹ̀lì ọlọ́pàá ní Ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú àwọn ènìyàn meedọ́gbọ̀n mìíràn rí lásìkò ìjọba olóògbé Sanni Abacha?

 

Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn náà fún yín.

Ní ọjọ́ kọkànlá Oṣù Kẹfà ọdún 1994, MKO Abiola kéde ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà. Nígbà náà ni Abacha fẹ́ gé orí rẹ̀, tí ó sì kéde pé MKO àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí Bola Ahmed Tinubu jẹ́ ọ̀kan lára wọn ni a ń wá.

Ọgagun olóògbé Sanni Abacha

Ẹ̀sùn wọn? Ìfẹ́hónúhàn (Treason).

Tinubu sá lọ, ó lọ sá pamọ sibi ìkọ̀kọ̀ ní ìlú Èkó. Ìdílé rẹ̀ kò mọ ibi tí ó wà títí tí ó fi pinnu láti lọ bẹ àbúrò rẹ̀, Sir Kafaru Oluwole Tinubu, tí í ṣe baba Adewale Tinubu, wò láti mú kí ọkàn wọn balẹ̀.

Oloye Obafemi Awolowo

Alhaji KO Tinubu gbà á Bọla nímọ̀ràn pé kí ó má ṣe máa sá mọ́, kí ó lọ fi ara rẹ̀ fún ọlọ́pàá ní ibùdó ọlọ́pàá èyíkéyìí.

 

Tinubu sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn náà. Wọ́n na án, wọ́n tì í, wọ́n fi ìbọn halẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì fi sí ẹwọ̀n sẹ́ẹ̀lì ọlọ́pàá tí ó yẹ fún ẹni mẹ́rin ṣùgbọ́n tí wọ́n fi ẹnìyàn meedọ́gbọ̀n sí, ó sì dúró níbẹ̀ fún ìgbà pípẹ́.

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ń wo sakun ọrọ

Lẹ́yìn àkókò diẹ Adájọ́ kan fọwọ́ sí beeli àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọlúwàbí kan, Bola Tinubu jẹ́ ọ̀kan lára wọn.

 

Àwọn ológun binú gidigidi sí Adájọ́ náà.

Adájọ́ tí ó fọwọ́ sì beeli náà ni Dr. Ibrahim Sulu-Gambari, ẹni tí ó padà wá di Emir kọkànlá ti Ilorin ní August 28, 1995.

 

Lẹ́yìn ìtúsile rẹ̀, wọ́n bombú ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n ìtàn míràn ni èyí fún ọjọ́ míràn.

 

TA NI KO TINUBU?

Òun náà ni ẹni tí Tinubu sọ ìfẹ́ rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ òṣèlú fún ní nǹkan bí ọdún 1989.

Òun náà ni ó mú un lọ sọ́dọ̀ Prince Tajudeen Oluyole Olusi, Ọmọ Ọba Èkó àti olóṣèlú tí ó ní ìrírí púpọ̀ (Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè fún Awolowo, lásìkò idìbò àti ìyàn ni sípò ní 1962 ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n).

 

Òun náà ni ó mú un wọ inú ẹgbẹ́ Primrose, ẹgbẹ́ òṣèlú kan nínú SDP tí olùdíje Gómìnà Èkó nígbà náà, Chief Oladapo Babatunde Sarumi ń darí, ẹgbẹ́ onígboyà náà sì kọ́ ọ nípa òṣèlú, ìṣàkóso àti agbára.

Sanni Abacha olóògbé MKO Abiola àti Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu

Ọjọ́ kan a ó sọ̀rọ̀ nípa ẹgbẹ́ Primrose, Justice Forum àti Mandate Group ti Ìpínlẹ̀ Èkó.

Ọkùnrin náà, ìdílé Tinubu àti àwọn míràn ni wọ́n gba ẹ̀mí Tinubu là gan-an tí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti sá kọjá sí orile-ede olominira Benin Republic nípasẹ̀ ojú ọ̀nà NADECO tí ó wà nínú igbó.

 

“Òun ni odi mi ní àkókò òkùnkùn inúnibíni. Òun ni àpáta mi”

Báyìí ni Ààrẹ Tinubu ṣe ń ṣàpèjúwe Baba Adewale Tinubu…

Sir KO Tinubu.

 

OJB News Yorùbá

One thought on “NIBO LEYIN N GBE, NIBO LEYIN WA NIGBA TI ÀÀRẸ BỌLA AHMED TINUBU SUN ṢẸẸ̀LI ỌLỌPA L’AYE SANNI ABACHA”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.