Ìdìbò gbogboogbo 2027: BÁYÌÍ NI TINUBU ṢE DALẸ ÀWA GÓMÌNÀ MÁARÚN TO YÀN WIKE L’AYO

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Abameta, 17, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Engr. Seyi Makinde ti sọ ojú abẹ níko bí ó ṣe tú àṣírí ńlá kan nípa bí Ààrẹ Bọlá Ahmed Tinubu ṣe dẹ̀ ẹ sí àwọn Gómìnà PDP márùn-ún tí wọ́n ṣiṣẹ́ fún un láti di Ààrẹ lọ́dún 2023.

Gómìnà Seyi Makinde lápá òsì, Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu láàrin méjì nígbà tí minisita fún ìlú Abuja Nysom Wike wá lápá òsì wọn

Gómìnà Makinde nígbà tó ń sọ̀rọ̀, ó sọ pé lẹ́yìn tí àwọn Gómìnà PDP márùn-ún tí wọ́n ń pè ní G5 ti ṣiṣẹ́ takuntakun fún Tinubu nínú ètò ìdìbò Ààrẹ ọdún 2023, Ààrẹ Tinubu fúnrarẹ̀ ló pè Seyi Makinde, ó ní kó lọ yan ẹni tí yóò jẹ́ Mínísítà ètò ìṣúná-owó orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá.

Aare Bola Ahmed Tinubu rèé to fi ọwọ lẹ ràn-án tó ń wo ìṣe àwọn òṣèlú alátakò

Makinde sọ pé ní tòótọ́, òun fa ọ̀gbẹ́ni Bimbo Adekanmbi, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú ọ̀rọ̀ ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣúná-owó sílẹ̀ fún Ààrẹ Tinubu gẹ́gẹ́ bí Mínísítà ètò ìṣúná-owó.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Irú kín lè leyii ooo, ẹ wo bí àwọn ajinigbe Bandiiti seji Bale ilé kàn, ìyáwo rẹ àti ọmọ oṣù mẹ́fà gbé tí wọn ń béèrè milionu lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà owó itusile ni ipinlẹ Kaduna….

*Lásìkò tí aráyé ro pe o títàn, tí ìrètí tí ja ṣòfò ni Ẹgbẹ́ agbaboolu Manchester City dín dundu ìyá jẹ́ fún ẹgbẹ́ agbaboolu Liverpool FC, ní wọn ba yà àgbàdo háà fìdí ọta lẹ́nu…..

Sùgbọ́n nígbà tí ó yá, Ààrẹ Tinubu kò mú Bimbo Adekanmbi tí òun mú lọ, dípò bẹ́ẹ̀ ló lọ mú Ọ̀gbẹ́ni Adebayo Adelabu Penkelemesi tí òun kò mọ̀ rárá gẹ́gẹ́ bí Mínísítà.

Gómìnà Seyi Makinde nile Ìjọba ipinlẹ Ọyọ

Gómìnà Makinde fi kún un pé, ìwà ọ̀dálẹ̀ ni èyí, nítorí pé ó fi hàn pé Tinubu dálẹ̀ gbogbo àwọn Gómìnà PDP tí wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un láti wọlé gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, àfi Gómìnà Nyesom Wike ti Ìpínlẹ̀ Rivers nìkan soso tí ó jẹ̀rè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe fún un.

 

Ọ̀rọ̀ yìí ti fa ariwo ńlá lórí ẹ̀rọ ayélujára àti nínú òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

 

OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀lé ìròyìn yìí fún yín.

One thought on “Ìdìbò gbogboogbo 2027: BÁYÌÍ NI TINUBU ṢE DALẸ ÀWA GÓMÌNÀ MÁARÚN TO YÀN WIKE L’AYO”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.