Ọlọ́run ò! Ọ̀PỌ̀ ỌMỌ ẸGBẸ́ APC TÍ ÌPÍNLẸ̀ BENUE LONI ÌJÀMBÁ ỌKỌ̀ LÁSÌKÒ TÍ WỌN FẸ ṢE ÌPOLONGO ÌBÒ FÚN TÍNUBU

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ A, 11, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Orí lo kò àwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress APC tí ipinlẹ Benue yọ lọjọ Abamẹta, Ọjọ Kẹwaa Oṣu Kẹwaa Ọdun 2026 bi ọkọ akẹrù meji to n gbe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lati ipinlẹ Benue yọ ninu ijamba buburu ni ilu Lafia, olu-ilu ipinlẹ Nasarawa.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ọmọ ẹgbẹ naa n lọ si ibi Apejọ nla tí ẹka àárín gbùngbùn Ariwa (North Central) fun atilẹyin saa keji fun Aare Bola Ahmed Tinubu ati Igbakeji rẹ, Kashim Shettima ti wọn ṣe nilu Lafia.

Àwòrán ọkọ toni ijamba pẹlu awọn èrò

BÍ IṢẸLẸ NAA ṢÉ ṢẸLẸ:

Lẹ́yìn ọjọ kan  ti awọn Gomina àárín gbùngbùn ariwa ti fọwọ si atilẹyin Tinubu fun saa keji.

Awọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú APC ni ipinlẹ Benue wọnyi jade ni kutukutu owurọ Ọjọ Abamẹta lati lọ síbi apejọ naa.

Àwòrán ijamba oko

Ijamba ọkọ naa waye ni agbegbe Government House Junction, ni inu ilu Lafia, ó kú diẹ ibuso  kilomita si ibi ti wọn ti n ṣe apejọ naa.

Awọn ẹlẹri oju ṣẹlẹ sọ pe ọkọ akero ti wọn wà ninu rẹ ni ijamba bí ó ṣe ní ìdojúkọ pẹlu ọkọ miiran to n bọ lọna ọtọtọ.

KÍNNÍ ÒTÍTỌ́ NÍPA ÌRÒYÌN IKÚ TÍ A GBỌ?

Iròyìn ti o n tan kaakiri pe ọpọlọpọ kú kii ṣe otitọ. Alukoro ẹgbẹ APC ti o ṣe oloootọ si Akọwe Ijọba Apapọ (SGF), Sẹnetọ George Akume, ti o n jẹ Dan-Morgan Ihomun ti fidi rẹ mulẹ.

O sọ pe:

“Otitọ ni pe awọn alatilẹyin APC kan láti ipinlẹ Benue (awọn ikọ tí ó ṣe lóòótọ́ si SGF) kopa ninu ijamba ọkọ ayọkẹlẹ loni nigbati wọn n bọ fun apejọ nla fun Aare Bola Tinubu. Ijamba naa ṣẹlẹ laarin Lafia, a dupẹ lọwọ Ọlọrun ko si ẹni ti o ku ṣugbọn awọn ti o farapa ni wọn ti gbe lọ si ile-iwosan.”

Ọpọlọpọ farapa to farapa ni wọn si ti gbe wọn lọ si awọn ile-iwosan oriṣiriṣi ni Lafia fun itọju pajawiri.

Ko si ẹnikẹ́ni tí a ti fidi royin ikú rẹ múlẹ̀ titi di àsìkò tí a ń gbé ìròyìn yìí jáde.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Àwọn òbí àwọn agunbaniro tí wọn jì gbé ní Ìpínlẹ̀ Imo tí jáde sọ̀rọ̀ sókè, eyii ni òun ti wọn sọ nípa ìjọba àti àwọn ẹsọ alaabo gbogbo…..

Apejọ naa jẹ apejọ nla ti gbogbo Ariwa pejọ si lati polongo fun idibo gbogbogbo 2027, ati pe Aya Ààrẹ, Sẹnetọ Oluremi Tinubu paapaa ni wọn n reti níbẹ̀.

 

A gbadura pe Ọlọrun mu awọn ti o farapa larada kikan.

One thought on “Ọlọ́run ò! Ọ̀PỌ̀ ỌMỌ ẸGBẸ́ APC TÍ ÌPÍNLẸ̀ BENUE LONI ÌJÀMBÁ ỌKỌ̀ LÁSÌKÒ TÍ WỌN FẸ ṢE ÌPOLONGO ÌBÒ FÚN TÍNUBU”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.