Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 10, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ariwo ayọ̀ àti ìdùnnú ni ó gbà ẹnu àti ọkàn àwọn òbí àwọn agunbaniro tí wọn jì gbé, bẹẹni ayọ̀ nla gba ọkàn gbogbo olùgbé ipinle Oyo ati gbogbo ilẹ Yoruba bi awọn ọmọ ile-iwe ti n lọ fun eto National Youth Service Corps (NYSC) ti awọn ajinigbe ji gbe ti di ominira.
Aafin Olubadan ti ilu Ibadan lo fi idi rẹ mulẹ ninu atẹjade kan ti o jade ni ọjọru, Ọjọbọ.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti Oluranlọwọ lori eto iroyin fun Olubadan ilẹ Ibadanland, Adeola Oloko, fọwọ si, Gomina ipinlẹ Imo, Sẹnetọ Hope Uzodimma, lo fidi rẹ mulẹ ninu ifọrọwerọ lori ẹrọ ibanisọrọ pẹlu Olubadan ilẹ Ibadanland, Kabiyesi Ọba Rashidi Adewolu Ladoja, ni bii aago marun irọlẹ oni.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Titi di asiko yii, a ko ti sọ bi wọn ṣe ri ominira naa gbà boya owo irapada ni wọn san tabi ipa awọn ologun lo, ṣugbọn ohun ti o ṣe pataki ni pe wọn ti wa ni alafia.

Aafin Olubadan dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti o sa ipá ati Gomina Hope Uzodimma fun akitiyan rẹ lati rii daju pe awọn ọmọ wa pada lailewu.
A o ma mu alaye kikun wa fun yin bi iṣẹlẹ naa ṣe n tẹsiwaju lori OJB News Yoruba
OJB News Yorùbá – Ohùn Otitọ!

One thought on “Ọpẹ óò! ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ NYSC TÍ WỌN JÌ GBÉ TÍ GBA ÒMÌNIRA OLUBADAN TÍ FÌDÍ RẸ MÚLẸ̀”