ILE ISẸ ỌMỌ OLÒGÚN GBÉ ORÚKỌ ÀWỌN MEEDOGBON TOKU NÍNÚ BAALU NAF 931 NILU IGBỌKỌ́DA

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 6, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu Naijiria (NAF) ti gbé orukọ awọn eniyan marundinlọgbọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu NAF 931 ti o ja ni agbegbe Igbokoda, ni Ipinlẹ Ondo sita.

 

Gẹgẹ bi atẹjade ti NAF fi sita, awọn eniyan 25 ni o wa ninu baluu naa – awọn awakọ ati oṣiṣẹ marun-un ati awọn ero ogun.

Baluu naa wa lori iṣẹ deede lati Benin lọ si Eko nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ. Titi di bayi, a ko ri ẹnikẹni ti o ye ninu wọn.

Ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu sọ pe iwadi kikun ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba naa.

 

Wọn si rọ gbogbo ara ilu lati yago fun arosọ ati kaakiri iroyin ti a ko fidi mulẹ, ki wọn si bọwọ fun aṣiri ati iyi awọn idile ti ajalu naa kan.

ÀWỌN TÓ KÚ NÍNU ÌJÀMBA NÁÀ:

ÀWỌN AWAKỌ̀ ÀTI OṢIṢẸ́ BÀLÚÙ (CREW – 5)

Squadron Leader MI Aburime — Flight Captain (Olori Awakọ)

Squadron Leader AP Man-Ugwueje — Co-pilot

Flight Lieutenant IS Bako — Co-pilot

Warrant Officer Abubakar A — Aircraft Technician

Corporal Uguru HC — Aircraft Technician

ÀWỌN ERO INU BÀLÚÙ (PASSENGERS – 20)

Flight Lieutenant TL Lazarus

Flight Lieutenant M Akinloye

Flying Officer IM Adeshina

Master Warrant Officer Onwuka F

Master Warrant Officer Matini BA

Warrant Officer Nuhu FS

Flight Sergeant James RB

Flight Sergeant Mohammed AI

Sergeant Ani AE

Sergeant Izibenikien SI

Sergeant Alafuka C

Sergeant Mbadugha AN

Lance Corporal Ugwuba FC

Lance Corporal Eledan GE

Mrs Ezeh Nneka

Godstmine Tarabina

Joy Micheal

Sunday Micheal

Ukeme David

Gideon Omotola

Ile-iṣẹ NAF fi ikẹdun rẹ ranṣẹ si awọn idile, awọn ọrẹ ati awọn akẹgbẹ iṣẹ gbogbo awọn ti o ku ninu ajalu ọjọ Aje naa.

 

Ki ọkàn gbogbo awọn to papoda maa ba Ọlọrun gbe. Ki Ọlọrun fun awọn idile wọn ni okun lati gba adanu nla yi.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu tí kéde ibanikedun Ọlọjọ mẹta fún àwọn ọmọ ológun tí Baalu wọn jà nilu Igbokódà. Minisita fún ọrọ irinajo ọkọ ofurufu Festus Keyamo náà tí jáde sọ̀rọ̀.

OJB News Yorùbá yoo tẹsiwaju lati mu iroyin kẹkẹẹ wa fun yin bi iwadi ba n tẹsiwaju.

One thought on “ILE ISẸ ỌMỌ OLÒGÚN GBÉ ORÚKỌ ÀWỌN MEEDOGBON TOKU NÍNÚ BAALU NAF 931 NILU IGBỌKỌ́DA”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.