ÀÀRẸ BỌLA TINUBU KÉDE ÌDÁRÒ ỌLỌJỌ MẸTA LÁTÀRÍ BAALU ỌMỌ OLOGUN TO JÁ NI IGBỌKỌ́DA

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolaji Salami, Òndó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 6, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ 

 

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu, ti kede idaro ọlọjọ mẹta fun awọn ọmọ-ogun ofurufu ti wọn ku ninu iṣẹlẹ ijamba baluu to waye ni ọjọ Aje.

 

Baluu ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu Naijiria, ti nọmba idanimọ rẹ jẹ NAF 931 / NGR 931, jẹ ti iru ATR-42-500MP Surveyor, baluu ẹlẹrọ meji ti wọn n lo fun iṣọ ati aabo eti omi.

Àwòrán Baalu ọmọ ológun to ja nilu Igbokódà

Baluu naa ja nitosi ibudo awọn ọmọ-ogun oju omi to wa ni Igbokoda, ni Ipinlẹ Ondo.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ṣé lóòótọ́ nipe Wàhálà túntún tí wá lọrun ilé ifowo pamọ GTB bí Agba oṣere Nollywood ilẹ̀ wá nnì, Yẹmi Solade ṣe fi ẹ̀sùn kan wọn, Eyii ni òun ti a mọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà…

GBOGBO ẸMI ÈÈYÀN MEJILELOGBON (32) LÓ SỌNÙ PÁTÁPÁTÁ 

Minisita fun irinna ofurufu, Festus Keyamo SAN, ti fidi rẹ mulẹ pe gbogbo eniyan mejilelọgbọn ti o wa ninu baluu naa lo ku.

Àwòrán minisita fún ètò irinna ọkọ ofurufu, Festus Keyamo pẹlu Baalu to ja

Ninu wọn, marun ni awọn awakọ ati oṣiṣẹ baluu naa, nigba ti marundinlọgbọn ku jẹ awọn ero inu rẹ.

 

Gẹgẹ bi alaye Minisita naa, baluu naa gbera ni Ilu Benin ni owurọ ọjọ Aje, ọjọ karun-un, oṣu kẹwa, ọdun 2026, o si n lọ si Eko.

Festus Keyamo minisita fún ọrọ ọkọ ofurufu

Ni nnkan bi agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹtala owurọ, atọna rẹ sọnu loju ofurufu, ibudo atọna ko si le ri i mọ. Ko pẹ pupọ lẹhin naa ni iroyin jade pe o ti ja lulẹ nitosi Igbokoda.

 

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn ọmọ-ogun oju omi ati awọn araalu ṣi n wa awọn ku baluu naa ni ibi iṣẹlẹ naa, ti iwadi si n lọ lọwọ.

Aare Bola Ahmed Tinubu pẹlu àwòrán ọkọ ofurufu tó já nilu Igbokódà

ÀÀRẸ TINUBU KẸDÙN, Ó PÀṢẸ KÍ ÀSÌÁ FÒ LÁÀBỌ́

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Aarẹ, Bayọ Onanuga, fi sita ni irọlẹ ọjọ Aje, Aarẹ Tinubu sọ pe Oga Agba ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu, Air Marshal Sunday Kelvin Aneke, ti fi ẹkunrẹrẹ iroyin ijamba naa to oun leti.

 

Aarẹ kẹdun pẹlu awọn mọlebi awọn ologun naa, o si tun ba gbogbo ile-iṣẹ ọmọ-ogun ofurufu ati ile-iṣẹ ọmọ-ogun Naijiria lapapọ kẹdun awọn akẹgbẹ wọn.

 

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Tinubu sọ pe:

“Akoko ibanujẹ nla gba a niyi fun awọn ọmọ-ogun wa ati fun gbogbo orilẹ-ede yii lapapọ. Awọn ologun ofurufu wa fi ẹmi wọn lelẹ lojoojumọ lati daabo bo orilẹ-ede Naijiria. A ko ni gbagbe ifẹmi-ara-ẹni-rubọ wọn.”

Aarẹ gbadura fun awọn to ku naa ki Ọlọrun tu awọn ẹbi wọn ninu.

 

Bakanna, Aarẹ paṣẹ ki gbogbo aṣia orilẹ-ede maa fò laabọ jakejado Naijiria fun ọjọ mẹta, lati bu ọla fun iranti awọn akọni ologun naa.

 

O tun paṣẹ ki iwadi to jinlẹ bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ lati mọ ohun to ṣokunfa ijamba naa, lati le dena iru rẹ lọjọ iwaju.

Àwòrán awako ofurufu náà rèé nígbà tí ó ṣe ìgbéyàwó lọṣẹ mẹta sẹ́yìn

Eyii tí ó gba omi lójú èèyàn ju ni ti Arákùnrin awako Baalu òun ti o ṣẹṣẹ ṣe ìgbéyàwó láàárín ọ̀sẹ̀ mẹta sẹ́yìn bai kí ó tó pàdé ikú òjìji.

 

Ṣáájú lai ro tẹ́lẹ̀ ni ìròyìn ibanujẹ yìí kan gbogbo èèyàn lára lójijì ni ọjọ Aje àná, lairo ti Lowurọ ọjọ aje oni, ọjọ karun-un oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni iroyin jade pe ọkọ baluu kan ti ja lorilẹede Naijiria.

 

Àwòrán minisita fún ètò irinna ọkọ ofurufu, Festus Keyamo pẹlu Baalu to ja

EYII NI BI BAALU ỌMỌ OLÒGÚN ṢE JÁ LU’LẸ̀ NILU IGBOKÓDÀ 

Ni owurọ ọjọ Aje ni baluu naa gbera ni Ilu Benin to si n lọ si ilu Eko pẹlu eeyan mejilelọgbọn ninu rẹ. Marun ninu wọn jẹ awọn awakọ ati oṣiṣẹ baluu naa ti awọn marundinlọgbọn yoku jẹ ero to ko.

Nnkan bi agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹtala ni atọna rẹ sọnu loju ofurufu ti ibudo atọna baluu ko si rii kan simọ.

Ko pẹ pupọ si asiko yii ni iroyin jade pe baluu naa ti ja lulẹ nitosi ibudo awọn ọmọogun ojuomi to wa ni ilu igbọkọda ni ipinlẹ Ondo

Alaye ti minisita fun irinna ofurufu, Festus Keyamo ṣe ni pe nọmba idanimọ baluu naa ni NGR 931 tabi NAF 931, Ẹya baluu ATR-42-500MP Surveyor ni baluu naa.

Iwadii ti a ṣe fihan pe irufẹ awọn baluu yii jẹ ẹlẹnjini meji ti wọn maa fi n ṣe amojuto ati idaabobo awọn etido atieti omi gbogbo,

Awọn ọmọogun oju omi ati araalu ṣi nwa awọn eeyan to wa ninu rẹ lẹyin ti wọn ṣawari ibi ti baluu naa ja si

Àwọn ẹrú àwọn èèyàn tó pàdánù èmi wọn sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Lọwọ ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ni awọn iroyin nipa ijamba naa ṣi n jẹyọ lẹyọ ẹyọ ni ati pe iwadi nlọ lọwọ.

Èèyàn 32 ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú tó já lulẹ̀ ní Igbokoda-Festus Keyamo, Mínísítà ìrìnàjò òfurufù

Àwòrán minisita fún ètò irinna ọkọ ofurufu, Festus Keyamo pẹlu Baalu to ja

Festus Keyamo (SAN) lapa osi, ọkọ ofurufu to ni ijamba lapa ọtun.Oríṣun àwòrán,Festus Keyamo (SAN)/FB/Getty images

Minisita fun irinajo ofurufu lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo, (SAN), ti fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mejilelọgbọn (32) lo wa ninu ọkọ ofurufu awọn ologun to jabọ n’Igbokoda, ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.

 

Ninu atẹjade ti Keyamo fi sita lọjọ Aje oni lo ti ṣalaye, pe ọkọ ofurufu naa poora lasiko irinajo lati Benin lọ si Eko, ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja iṣẹju mẹtala aarọ.

 

Nọmba baaluu ọhun bi Keyamo ṣe wi ni “NGR 931.”

 

Iroyin naa ṣi n tẹsiwaju lori OJB News Yorùbá. A o ma mu alaye kẹkẹẹ si yin wa bi iwadi ba n tẹsiwaju.

One thought on “ÀÀRẸ BỌLA TINUBU KÉDE ÌDÁRÒ ỌLỌJỌ MẸTA LÁTÀRÍ BAALU ỌMỌ OLOGUN TO JÁ NI IGBỌKỌ́DA”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.