Orísun: OJB News Yoruba | On’kotan: Lekan Lawal, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aiku, 23, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Se e rántí ibi tí mo bá ìtàn mi de, ọlọpaa tí wá kò wá, wọn mú mi lọ sí tesan wọn, mi ò mọ ibi tí Misita Cole wá, bẹẹni Mrs Cole, gbogbo rẹ tí dàrú mọ mi lójú, mo sì ń kabamo nínú ọkàn mi, ẹ jẹ ká tẹ̀síwájú.
Wọ́n gbé mi dé tẹ́ṣàn Sango, wọ́n tì mí sínú sẹ́ẹ̀lì. Òórùn ìtọ̀ àti òógùn ń pa mí lẹ́nu.
Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, DPO tẹ́ṣàn náà wọlé. Kì í ṣe ẹ̀gbọ́n Ọ̀gbẹ́ni Cole mọ́. Obìnrin ni, ojú ẹ̀ le bí òkúta.
“Olawale Joseph Oladejo ,” ó pè orúkọ mi pátápátá. Mo gbọ̀n. Báwo ni ó ṣe mọ orúkọ bàbá mi?
“Ẹnìkan fi fídíò ránṣẹ́ sí OJB News Yoruba lánàá. Fídíò tí Ṣọ́lá ya. Gbogbo Sango-Ọta ti rí i lórí Facebook.” Ó fi fóònù hàn mí. Háà! Fídíò tí Ọ̀gbẹ́ni Cole ń yọ ìbọn, tí Mrs. Cole ń sọ pé ‘míliọ̀nù mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn òyìnbó’ ti kún gbogbo orí internet.
“Ọ̀gbẹ́ni Cole àti ìyàwó ẹ̀ ti sá lọ,” DPO sọ. “Wọ́n sá lọ sí Cotonou lálẹ́ àná.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ṣùgbọ́n ìwọ nìkan ló wà níbì.”
Inú mi bàjẹ́. “Madamu DPO, mo jẹ̀bi o, ṣùgbọ́n wọ́n fi tipátipá mú mi. Wọ́n ní wọn á pa mí!”
DPO wo mí lójú. “Owó míliọ̀nù márùn-ún tí ó wà lọ́wọ́ ẹ da? Owó ìwà ọ̀daràn ni. Ṣùgbọ́n…” Ó dákẹ́ díẹ̀.
“Ṣọ́lá ti wá síbí. Ó ní kó o jẹ́ ẹlẹ́rìí. Bí o bá sọ gbogbo òtítọ́ fún àwa àti ICPC, a máa dáàbò bo ọ́. A ó sì fún ọ ní ‘witness protection’.”
Mo mí ìmí ààyè. “Mo ṣetán ma. Mo máa sọ gbogbo ẹ̀.”
Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta
Mo kọ gbogbo ìtàn sínú ìwé. Bí Ọ̀gbẹ́ni Cole ṣe ń ta ọmọ fún àwọn òyìnbó, bí wọ́n ṣe ń lò mí gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ọmọ, bí wọ́n ṣe fi ìbọn dẹ́rùbà mi.
DPO tẹ́tẹ̀ sí fóònù. “Ẹ gbé Joseph lọ sí safe house ní Ikeja. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí ó wà.”
Ní alẹ́ ọjọ́ náà, mo wà nínú yàrá kan ní Ikeja. Tẹlifíṣàn ń fihàn ìròyìn: “Couple on the run: Sango-Ọta landlord wanted for child trafficking to Europe. Police declare them wanted. Victim Joseph O. in protective custody.”
Mo pa TV, mo wo àpò owó míliọ̀nù márùn-ún náà. ICPC ti gba á lọ́wọ́ mi. Wọ́n ní ó jẹ́ ‘ẹ̀rí’. Inú mi dùn, inú mi sì bàjẹ́. Mo ní ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n mo padà di aláìní.
Kò pẹ́, ẹnìkan kàn lẹ̀kùn. Mo dìde kánkán. Ṣọ́lá ló yọjú.
“Joseph, ẹ kú ìjà,” ó sọrọ, bẹẹ ó ń rẹ́rìn. “Mo ti rán gbogbo fídíò sí OJB News Yorùbá. Lái pẹ́, gbogbo ayé á mọ̀. Ọ̀gbẹ́ni Cole ò ní lè sá mọ́.”
“Ṣé o mọ̀ pé wọ́n ní ìbọn?” Mo bi í.
“Mo mọ̀. Ìdí nìyẹn tí mo fi kó àwọn Boys ti Sango bá ẹ. Àwa la máa ṣọ́ ọ.” Ó ju búrédì àti ẹ̀wà sí mi. “Jẹun. Ọla la máa lọ sí kootu. Ìwọ ló máa gba dájọ́ rere.”
Mo jẹun, ṣùgbọ́n orun kò kún ojú mi. Mo ń ronu Mrs. Cole. Mo sì rántí Ọ̀rọ̀ ẹ̀ ikẹ́yìn: “Má ṣe jẹ́ kí ọmọ mi kú nínú o!”
Sé ó ti lóyún ní ti ní tòótọ́ ni? Sé ọmọ náà wà láàyè? Sé èmi ni bàbá ọmọ náà? Àwọn ìbéèrè yìí ni mo ń bí ara mi.
Nígbà tí mo fẹ́ sùn, fóònù safe house bẹ̀rẹ̀ sí dún. Nọ́mbà Private. Mo gbé e pẹ̀lú ìbẹ̀rù.
“Joseph…” Ohùn obìnrin kan ló ń sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́. “Èmi ni Mrs. Cole. A wà ní Benin Republic. Mo ti lóyún. Ọmọ rẹ ni. Ṣùgbọ́n Ọ̀gbẹ́ni Cole fẹ́ ta ọmọ náà nígbà tí mo bá bí. Gbà mí, Joseph. Bí o kò bá gbà mí, n ó pa ara mi àti ọmọ rẹ ni o.”
Ó dá ìpè sílẹ̀ kùkù, bẹẹ lopa ago ìpè momi létí.
Mo wo Ṣọ́lá tí ó ń hòrùn lórí ṣófà.
Báwo ni mo ṣe máa gbà á? Ṣé mo máa fi ẹ̀mí mi wéwu fún obìnrin tí ó fẹ́ fi mí ṣe ẹrú ọmọ? Ṣùgbọ́n ọmọ náà… ẹ̀jẹ̀ mi náà ni.
A máa tẹ̀ síwájú… Apá Kẹfà
