KO TÍ SÍ IJỌBA TIWA Ń TÍWÁ NILẸ ÁFRÍKÀ BAYI – Obasanjo

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Abameta, 23, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Gẹgẹ bi Oloye Olusegun Obasanjo ṣe sọ ni Bauchi ni ọsẹ yii, ko si democracy tootọ ni Afirika, ohun ti a ni ni Western Liberal Democracy ti awọn oyinbo fi ipa mu wa lati gba.

Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ń wo sakun ọrọ

Kini Obasanjo sọ ninu ifọrọwerọ naa:

“A ko fun wa ni ohun miiran, a gba ti wọn gẹgẹ bi a ṣe ri. Ṣe o ti ṣiṣẹ? Ṣe o n ṣiṣẹ? Ṣe yoo ṣiṣẹ? Awọn ibeere wọnyi ni a gbọdọ beere.”

​

“Ìjọba àwa a rawa ti o n ṣiṣẹ yẹ ki o mu ire ati alafia fun gbogbo eniyan, aabo ẹmi ati dukia, ko si iyasọtọ.”

Obasanjo ni Western democracy dagba lati inu ijọba ọba, nitorina wọn ni “government and loyal opposition” ti o jẹ olotitọ si ọba. Ṣugbọn ni ede Yoruba ati ọpọlọpọ ede Afirika, opposition tumọ si ọta. Nitorina o di “loyal enemy” — kini o ṣe si ọta rẹ? O fọ ọ run!

O tun beere: “Kini idajọ n ṣe ninu ijọba? Bawo ni awọn eniyan miliọnu ṣe dibo, ti awọn eniyan marun-un yoo wa sọ pe idibo naa ko wulo? Ṣe iyẹn ni democracy?

Eyii ni ojú àwọn aṣojú ayédèrú àjọ ileeṣẹ ọba káàkiri ipinlẹ mokanlelogun àti ní Amẹ́ríkà àti Chaina

 

 

O ni aṣọ ti a ko wọn fun ọ ti o ba wọ, yoo jẹ kekere tabi nla ju — ko ni wọ ọ, gẹgẹ ni democracy ti a ya lati ode ko ba Afirika mu.

Goodluck Jonathan ati Peter Obi tun sọ pe agbara pupọ wa ni ọwọ Ààrẹ ní kan soṣo ni Naijiria, o yẹ ki a pin agbara bi Switzerland tabi pada si parliamentary system.

 

Apakan  ijiroro yii — Obasanjo n ṣalaye idi ti Afirika fi nilo democracy ti o ni akoonu Afirika ninu.

One thought on “KO TÍ SÍ IJỌBA TIWA Ń TÍWÁ NILẸ ÁFRÍKÀ BAYI – Obasanjo”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.