Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Abameta 22, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Aare Bola Tinubu ti paṣẹ fun mi mú lẹsẹkẹsẹ arákùnrin George Buchi Nwabueze ati idaduro awọn Permanent Secretary mẹta lẹhin ti wọn rii ile-iṣẹ iroja miiran ti n ṣiṣẹ ninu Office of the Secretary to the Government of the Federation (OSGF).
Awọn Permanent Secretary ti a daduro ni: M.S. Danjuma, Nadungu Gagare, ati Richard P. Pheelangwah.
Alaga ajọ ICPC, Dr. Musa Aliyu, SAN, lo sọ eyi fun awọn oniroyin ni State House ni ọjọ Jimọ lẹhin ti o ba Aare sọrọ fun igba keji ni ọjọ meji, lẹhin ipade Ọjọbọ.

Gẹgẹ bi ICPC ṣe sọ, ayédèrú ile-iṣẹ tuntun naa n jẹ “National Brands Development and Made-in-Nigeria Special Project Office” ti wọn fún ní office laifọwọsi ninu ọgbà ileeṣẹ ìjọba apapọ orile-ede yii, OSGF, laisi aṣẹ Aare.
“Lẹhin alaye siwaju si ti ICPC fun Aare lori iwadii ile-iṣẹ ayédèrú àjọ Presidential Foreign Intervention Promotion Council ati ailagbara ilana ni iṣẹ ijọba, ICPC ti ṣàwárí ayédèrú ile-iṣẹ miiran ti a pe ni National Brands Development and Made-in-Nigeria Special Project Office, ti a se agbekale rẹ sínú ileeṣẹ ọba OSGF,” gẹ́gẹ́ bí Aliyu ṣe sọ.
ICPC sọ pe oludasilẹ ayédèrú ile-iṣẹ naa ni Prince George Buchi Nwabueze ti n ṣiṣẹ pẹlu orukọ oriṣiriṣi marun: George Nathan, George Nathan Nwabueze, Honourable George Buchi Nwabueze, Prince George Buchi Nwabueze ati George Nwabueze, pẹlu awọn alabaṣiṣẹpọ ti a fura si ninu OSGF.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
Aare ti paṣẹ pe:
*Ki a mu Prince George Buchi Nwabueze lẹsẹkẹsẹ
*Ki a se idaduro awọn Permanent Secretary mẹtẹẹta naa lẹsẹkẹsẹ
Iṣẹlẹ ọjọ Jimọ yii jẹ tuntun ninu itanjẹ ti o bẹrẹ pẹlu ìfihàn ayédèrú àjọ ile-iṣẹ Presidential Foreign Intervention Promotion Council, ẹni ti oludari rẹ ti a pe ni Adeniyi Adeyemi Matthew n dojukọ ẹjọ ayederu ati afarawé eniyan.

Ayédèrú àjọ Ile-iṣẹ yii ni ile-iṣẹ ayédèrú kẹrin ti a ti ṣawari lẹhin PFIFC lati ibẹrẹ April.
OJB News Yorùbá yoo tẹsiwaju lati fun yin ni alaye.
