Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Temitope Hafsat Lawal | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje 10, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Wahala nla ti bẹ silẹ lori itẹ Awùjalẹ ti Ìjẹ̀bú-Ode. Ilé Fùsẹ́ngbùwà Ruling House ti yọ àwọn olórí mẹ́ta kúrò nitori ẹsun pe wọn gba owo abẹtẹlẹ lọwọ awọn ọmọ ilé ọba to fẹ jẹ Ọba.
Itẹ Awùjalẹ ti ṣofo lati July 2025 lẹhin iku Oba Sikiru Kayode Adetona to jẹ Ọba fun ọdun maarundinlaadorin (65) . Lẹhin naa, ọmọ ilé ọba bí maarundinlogorun (95) (ọkunrin 94, obinrin 1) jade lati dije.
KÍNNÍ Ó ṢẸLẸ?
*Ijọba Ogun labẹ Dapo Abiodun da eto yiyan duro lẹẹmeji ni January 2026 nitori ẹbẹ pipọ pe owo n ja, bribery wa.
*Police ati DSS pe gbogbo oludije wa si Ijebu-Ode lati ṣe alaye. Lẹta ti Ministry of Chieftaincy kọ ni Jan 20, 2026.
*Olórí ilé, Otunba Lateef Owoyemi, sọ pe ki Ijọba gba wọn laaye lati tẹsiwaju, o sọ pe ko si ẹnikan ti wọn ri pe o jẹbi sibẹ.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
*Awọn obinrin ilé naa, bi Aremobinrin Jadiara, lọ si Local Government lati tako pe wọn fẹ fi Ọba kan pa wọn lẹsẹ. Wọn ni “Itẹ Awùjalẹ jẹ mimọ, a ko gbọdọ ta fun owo”.
*Ọmọ ọba kan, Prince Tajudeen Bello ni “Itẹ Awùjalẹ ko gbọdọ lọ fun eni to san owo ju”.
Bayii, awọn mẹta ti wọn yọ kuro ni wọn n dupe lọwọ, Police n ṣe iwadii, gbogbo Ijebu n duro de tani yoo jẹ Awùjalẹ 60th.
OJB News Yoruba yoo ma mu imudojuiwọn wa fun yin.
