Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú 2, Oṣù Kẹjọ 2026.
*Ìṣẹ́gun tí ó yí ìtàn ayé rẹ̀ padà
Ọmọ Nàìjíríà tó ń jẹ́ aṣáájú-a-lagbàwí, Oba Femi tí wọ́n ń pè ní “The Ruler”, ti ṣe ohun tí kò sí ẹni tó retí – ó ṣẹ́gun ẹranko inú pápá ìjàkadi, Brock Lesnar nínú ìjà Hell in a Cell tó le koko níbi ayẹyẹ WWE SummerSlam 2026 Night One tó wáyé ní Minneapolis, Minnesota ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, August 1, 2026.
Ìjà yìí ni ìjà kẹta láàrín àwọn méjèèjì, ó sì ni ẹ̀jẹ̀ àti ìgbóná jù.
Báwo ni ìjà náà ṣe bẹ̀rẹ̀?
Gẹ́gẹ́ bí WWE ṣe kéde, ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní WrestleMania 42 nígbà tí Oba Femi gba ìpèníjà Lesnar, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ ní ọ̀nà tó yà gbogbo ayé lẹ́nu, títí Lesnar fi fi ibọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ nínú pápá bí ẹni pé òun fẹ́ fẹ̀yìntì.
Ṣùgbọ́n Lesnar padà wá ní Clash in Italy, ó fi F-5 méje lù Oba Femi, ó sì di ìjà náà mu 1-1.
Lẹ́yìn tí Oba Femi gba King of the Ring 2026, ó pe Lesnar, Lesnar sì dáhùn pé kí wọ́n má ṣe jà lásán, kí wọ́n jà nínú Hell in a Cell – ilé ẹ̀wọ̀n irin tó burú jùlọ.
IRÚFẸ́ ÌJÀ HELL IN A CELL:
Ìjà náà jẹ́ Main Event. Láìsí ìkọlù ọ̀fẹ́, Oba Femi bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú agbára, ó tì Lesnar mọ́ ẹ̀wọ̀n irin, ó sì fi tábìlì fọ́. Lesnar tún dáhùn pẹ̀lú Suplex City àti ìlù àga irin, ṣùgbọ́n ọmọ Nàìjíríà náà kò jáwọ́.
Ní ìkẹyìn, Oba Femi fi agbára rẹ̀ gba ìṣẹ́gun, ó sì di olúborí nínú ìjà mẹ́ta náà 2-1.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìjà
Ohun tó fà ẹ̀kún jáde ni ìṣe Lesnar lẹ́yìn ìjà. Lesnar padà wọ inú pápá, ó di Oba Femi mú, ó sì kéde níwájú àwọn ènìyàn pé: “Oun ni ọjọ́ iwájú WWE, èmi sì ni ti àtẹ́yìnwá”. Ó fi ọwọ́ yí padà bíi pé òun ti fẹ̀yìntì tòótọ́.
Pẹ̀lú ìṣẹ́gun yìí, Oba Femi ti di ọ̀kan lára àwọn akọni tó ga jùlọ ní WWE lọ́dún 2026, ó sì ti fi orúkọ Nàìjíríà sí orí tábìlì ayé.
