ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ BỌDE THOMAS ATI ÌṢUBÚ RẸ

Orísun: OJB News Yoruba | Onkorin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 29, Oṣù Keje 2026 

Mo kí gbogbo ẹyin olólùfẹ́ wa gbígbó kárí ayé pé a kú ọdún Kérésìmesì àti ọdún tuntun 2021,

Ọdún ayọ̀ àti opó àṣeyọrí ni ọdún 2021 yóò jẹ fún wa láṣẹ Èdùmàrè, mo fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo eyin alatileyin wá gbogbo kárí ayé

Ẹyin onibara ileese tewetegbo wá De-Rock Herbal Life Products Ltd, mo dúpẹ́ ó, àjọṣe wá ó ní ba jẹ ó, ẹyin ọrẹ wá lórí ìkànnì Oojiirebi, ẹ ṣeun, ẹ kù aduroti wá Olódùmarè ó ní padà lẹ́yìn gbogbo wa o

Lóni yìí, ìtàn gbajugba àti ọmọ Yorùbá àtàtà tó ń jẹ Ọmọọba Alfred Olabode Akanni Thomas, ti gbogbo eeyan mọ si Olabode Thomas là ó sọ fún wa lónìí, orúkọ rẹ lee ma nitumọ mọ niwaju awọn ọdọ iwoyi amọ arugbo rẹ ti se oge ri nilẹ yii, ekisa rẹ si ti lo igba ri.

Hmmm, lootọ orukọ Olabode Thomas lee ma jẹ ki awọn eeyan ranti adugbo kan ti wọn fi sọri rẹ ni agbegbe Surulere nipinlẹ Eko, amọ ohun ribiribi to se nile aye ko gbọdọ parẹ.

Bi Olabode Thomas ko tilẹ dagba tabi darugbo ko to jade laye, nitori ko lo ju ọdun mẹrinlelọgbọn lọ, to fi tẹri gbasọ, sibẹ a ko gbọdọ gbagbe akanda ọmọ Yoruba yii, tori ipa to ko si idagbasoke iran Yoruba ati Naijiria lapapọ

Gẹgẹ baa ti ri ka loju nínú ìwé ìtàn àti awọn ìwádìí mìíràn tí a ṣe, nígbà tí mo gbé yẹ̀ wo lọ tún losi, mo rí pé ó yẹ kí àwọn odo ìwòyí o ka nípa Balógun ìlú Oyo yìí, kí a sì rí ọgbọn ko nínú ìṣubú akọni ẹdá yìí,

Ìtàn ìgbésí ayé Olabode Thomas ree, àwọn àgbà bò wọn ní bi onirese ko ba fingba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ ko lee parun.

ỌMỌ TI WỌN FI ỌLÁ ÀTI OWÓ TÓ NÍ BODE THOMAS 

Osu Kẹwaa, ọdun 1919 ni Olabode Thomas de ile aye, iyẹn lẹyin ọdun marun un ti baba Naijiria, Lord Lugard so ẹkun ariwa pọ mọ guusu, ti wọn si di Naijiria kansoso

Olokoowo to gbajugbaja nilu Eko ni Andrew Thomas ati iyawo rẹ ti wọn jẹ obi Bode Thomas, ilu Ọyọ Alaafin ni wọn si ti wa sisẹ aje nilu Eko.

Koda, a si lee ni idile ọlọla ati olowo lo ti jade, ọmọ ti wọn fi ọla ati owo tọ lati kekere ni Bode Thomas.

Bode Thomas jẹ omiran ẹda, ẹni to ga, to si ṣigbọnlẹ bẹẹ, eyi to mu ki wọn fun ni orukọ inagijẹ ‘Buldozer’, bẹẹ si ni kii faaye gba ijakulẹ, to si maa n wa aseyọri ninu gbogbo ohun to ba dawọle

Ile ẹkọ girama CMS ti Samuel Ajayi Crowther da silẹ ni Bode Thomas lọ, to si bẹrẹ isẹ lọgan to pari iwe mẹwaa rẹ bii akọwe nileesẹ Reluwe ilẹ wa

Ìtàn sọ fún wa pé nigba to di ọdun 1939, ni Bode Thomas morile ilu London lati lọ kọ ẹkọ nipa imọ ofin, to si di agbẹjọro, to si di ojulowo lọya lọdun 1942, ko to pada wale lati wa da ileesẹ agbẹjọro tiẹ silẹ nilu Eko

Lásìkò yìí ni Bode Thomas, pàdé Frederick Rotimi William ati Remilekun Fani Kayode, ni àwọn meteeta bá jọ fi mọ sọ́kàn ni wọn ba dijọ da ileesẹ agbejoro kan naa silẹ, ti wọn pe orúkọ rẹ ni Thomas, Williams and Kayode law firm

O fe máa sì ibi tí òkìkí ileese wọn yìí ó kàn de óò, ní gbogbo àsìkò naa, ìgbà tó di ọdún 1946 ni Bode Thomas bá di agbẹjọro fun ẹgbẹ Ọmọ Odùduwà,lèyí to si tún fún ní anfaani lati jẹ ọkan lara awọn eeyan to da ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, taa mọ si ẹgbẹ Awolowo, Action Group silẹ

Nígbà tí yóò fi di ọdun 1949 yìí, òkìkí Bode Thomas tí kan kale ká oko gbogbo orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, lọ́dún 1949 yìí ni Aláàfin Ọyọ, Ọba Adeniran Adeyemi kejì bá ranse pé Bode Thomas láti wá joyè Balogun tilu Ọyọ o ,

BODE THOMAS JẸ BALOGUN TILU ỌYỌ TÁN, AT’ONILE ÀTI ÀLEJÒ LO Ń FÒ FAYO 

Lootọ ni Yoruba ni bí ọmọ ẹni ba dára ká wí, kii kúkú ṣe bí ti kafi ṣe aya ni, lọ́jọ́ iwuye Balogun tí Ọba Aláṣẹ èkejì òrìṣà, Ọba Adeniran Adeyemi fi Bode Thomas jẹ́ yìí, gbogbo ìlú Ọ̀yọ́ ló mọ pe awon gba àlejò lọ́jọ́ tá ń wí, níbi tí ọpọlọpọ àwọn Gbajumọ àti gbajugbaja olóṣèlú àti àwọn ọlọ́lá tí de báwọn lálejò n’ilu Ọyọ, ẹni tí kò lerin ni kí wọn ó gbé òun ni koko lọrun de gbàgede ìfinijoyè,

Orisirisi eléré ìbílẹ̀ àti àwọn asunjala, àwọn elegbejegbe pé silu Ọ̀yọ́ lọ́jọ́ náà lóhùn, àwọn ẹgbẹ́ olope lolugbalejo pàtàkì, ẹni ayesi ọjọ naa ni Oloye Obafemi Awolowo, irú ọjọ naa o se gbàgbé boroboro nínú ìtàn ìlú Ọyọ, bẹ́ẹ̀ ni Bode Thomas di Balogun n’ilu Ọyo,

Kínní kàn wàá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Bode Thomas jẹ òye Balogun tán n’ilu Ọyọ, kín ló ṣẹlẹ̀, àti pé nibo gan-an ni irin ajo ayé Bode Thomas fori sọ náà, ẹ pàdé mi ni apá kejì ìtàn yìí laipe, ẹ kù ojú lọnà,

Agbe mi ṣe tán ó ń rò de ikosun, Lekenleke mi ṣe tán ó ń rode ikẹ fún níní-ń-níní, Olalekan Akanji ikọ Ademeto Àtùpà ọmọ Bàbà ni Ijeru Ogbomoso ṣe tán mo ń relé Bàbà tóbi mi lomo, títí ọjọ́ min-ín ire oo

to lo lati fa oju awọn Ọba, ijoye ati eeyan jankan-jankan wa sinu ẹgbẹ oselu Ọlọpẹ, ti ero oun ati Oloye Obafemi Awolowo si saAba maa n yatọ lasiko ti wọn ba n jiroro ninu ẹgbẹ.

Bode Thomas di Minisita feto igbokegbodo ọkọ labẹ ofin Mcpherson lọdun 1951, to si n soju ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ibẹ si lo ti n fọnrere fun agbekalẹ ijọba awa ara wa lorilẹ-ede yii , to fẹ ko bẹrẹ lọdun 1956

Nigba ti wahala suyọ lori ofin Mcpherson losu kẹta, ọdun 1953 ni Bode Thomas kọwe fi ipo minisita silẹ, amọ o pada wa di minisita fun isẹ ode lẹyin ipade apapọ lori atunse ofin to waye nilu London

Itan fi ye wa pe bi Bode Thomas se jẹ ọlọpọlọ pipe ẹda to, naa lo ni ọkan giga to, eyi to mu ki ibasepọ oun ati awọn olori kan ma gun rara, to fi mọ Ọlọla Ahmadu Beloo ati Alaafin Adeyẹmi keji.

Bode Thomas jẹ oninu fufu ti kii pẹ binu, kii pa ọrọ mọra, o maa n sọ tinu rẹ jade lai fẹ mọ ẹniti ọrọ naa yoo bi ninu, eyi to maa n mu ko di ọta ọpọ eeyan

Nibi ipade igbimọ lọbalọba to waye lọdun 1953 eyi ti Bode Thomas jẹ alaga fun, la gbọ pe o ti yaju si ọba Adeniran Adeyẹmi, tii se baba Alaafin Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta to wa lori oye bayii, to si n sọrọ si ori ade naa pe ko dide duro lati yẹ oun si nigba ti oun wọle, gẹgẹ bi awọn Ọba alaye yoku to wa nikalẹ ti se

Iroyin kan ti ko fidi mulẹ, to n lọ lati atẹnudẹnu tun sọ pe ọrọ yii bi Ọba Adeyẹmi ninu to bẹẹ, to si ni ki Bode Thomas maa gbo lọ pẹlu bo se n bu oun yii, lọjọ kejilelogun, osu Kọkanla lẹyin ipade ti Bode dele rẹ ni Yaba nilu Eko lati Ọyọ, lootọ lo ba n gbo bii aja.

Wọn gbe Bode Thomas lọ silu Ijẹbu Igbo fun itọju, sugbọn nibẹ lo ti tẹri gbasọ lọjọ Kẹtalelogun, osu Kọkanla, ọdun 1953

Bode Thomas fẹ iyawo, ti orukọ rẹ n jẹ Lucretia Sobola Odunsi, to si bi ọpọ ọmọ. Lara wọn ni Ẹniọla ati Dapọ.

Ọmọọba Alfred Olabode Akanni Thomas ku togo-togo, ko gbe ile aye lati da awọn ara to wa ninu rẹ nitori ọdun mẹrinlelọgbọn pere lo se nile aye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.