*Ilu Ki Seyi Makinde – Awon ara Naijiria fe e!
*Ariwo nla ti n ja ninu oṣelu Naijiria!
Orísun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aje, 27, Oṣù Keje 2026.
Ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM) ti sọ kedere pe, ọkan awọn ọmọ Naijiria ti bale lórí Gomina ipinlẹ Ọyọ, Engr. Seyi Makinde, gẹgẹ bi ẹni to le gba ipò lọwọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ninu eto idibo ọdun 2027.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita, wọn ni idi ti awọn ara ilu fi n fẹ Makinde ni nitori iṣẹ takuntakun ati idagbasoke ti o n ṣe ni ipinlẹ Ọyọ. Wọn ni Gomina naa ti fi hàn pe o le ṣakoso orilẹ-ede naa ti o ba fun ni anfaani.
APM tẹnumọ pe, kii ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ara Naijiria ti ri iṣẹ Makinde, wọn si ti gba a gẹgẹ bi aṣayan ti o dara julọ ti o le mu iyipada rere wa.
Ọrọ yii ti fa ariwo nla lori ita, pẹlu ibeere nla to n beere pe, Ṣe Makinde gan-an yoo gba ipenija yii?
A n wo oju ọna naa!
