ỌWỌ TẸ ṢỌJA TÓ Ń TÀ OHUN EELO ÒGÚN FÚN ÀWỌN BANDIITI

*Private Mohammed Yusuf tí ó sá kúrò ní Ẹ̀ka rẹ̀ ní Èkó, tí ó fẹ́ sá lọ sí Cameroon, ni wọ́n tẹ́ ní Maiduguri

Orisun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aje, 27, Oṣù Keje 2026.

Ilé-iṣẹ́ Ologun Nàìjíríà ti fi agbára hàn pé kò sí ibikíbi tí àwọn atilẹyìn ajínigbé lè sá pamọ́ sí.

Àwọn ọmọ-ogun Operation HADIN KAI ti mú Private Mohammed Yusuf, 23NA/84/1939, tí ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe aṣọ àti ohun èlò ogun ní Èkó, lẹ́yìn tí wọ́n ti kede rẹ̀ pé wọ́n ń wá a lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù keje ọdún 2026.

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Captain Mohammed Goni, Alága Ìròyìn fún Operation HADIN KAI ṣe fúnni, wọ́n mú un ní agogo mẹ́fà àti ààbọ̀ ìrọlẹ́ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje ní Jidari Bus Stop, Maiduguri, nígbà tí ó ń gbìyànjú láti sá lọ sí orílẹ̀-èdè Cameroon.

Ìwádìí àkọ́kọ́ fi hàn pé afurasi yìí ti sá kúrò ní ibi iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ keje oṣù keje, ó sì ti sá pamọ́ sí agbègbè Gomari Costain ní Ìjọba Ìbílẹ̀ Jere pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ kan.

Àwọn ọmọ-ogun 7 Provost Group ni wọ́n mú un lẹ́yìn tí wọ́n gba ìròyìn tó péye gbáko lọ́wọ́ àwọn ará ìlú.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó wà lábẹ́ àtìmọ́lé 7 Provost Group, níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí pípé láti mọ ìwọ̀n ibi tí ó ti dé nínú ọ̀ràn yìí àti láti mọ àwọn mìíràn tí ó bá wà nínú rẹ̀.

Operation HADIN KAI tún tẹnumọ́ pé, yálà o jẹ́ ọmọ-ogun tàbí ará ìlú, kò sí ààyè àbọ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ran ajínigbé lọ́wọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.