NÍBI ÌPOLONGO ÌBÒ N’ILU EDE, ÀWỌN TOOGI OLÓṢÈLÚ KỌLU ÌYÀWÓ BỌLA OYEBAMIJI OLUDIJE GÓMÌNÀ APC

*Awon Agbero Toogi Yonjuwo Lu Iyawo Bola Oyebamiji Nigba To N Soro Fun Oko Re Ni Ede – Won Bo Gelee Re Danu!

*Iba Jo Ede Lana, Awon Odo Gba A Lowọ Iku Ofo

 

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje 3, Oṣù Kẹjọ 2026. 

 

Ilu Ede gbóná lánà! Eru ba gbogbo àwọn èèyàn agbegbe Oja Timi tí jìnnìjìnnì sì bo wọn mọ́lẹ̀.

Wahala nla lo sele lana ni ilu Ede, ni Ipinle Osun, nigba ti awon toogi alagidi ti won gun okada wọlé, ti won si kolu Dr. Sekinat Oyebamiji, aya eni rere Bola Oyebamiji, oludije Gomina ti egbe APC ni Idibo Osun ti o n bo lona.

Obinrin rere naa lo lati se ipolongo fun oko re, lati ba awon iyawo ati awon obinrin jẹ ninu ilu Ede soro, ki o le so fun won ni anfaani ti yoo wa ba won ti oko re ba di Gomina.

 

BÍ WỌN ṢE KỌLU U

Gege bi awon ti oju lo ri isele naa se so fun wa, gbogbo nkan n lo lọwọ laalaa, awon obinrin si n gbo adun oro iyawo oludije naa, nigba ti awon toogi mefa ti o wa lori okada meta ya bo agbegbe naa.

Won bere si ni kigbe pe “Ẹ tu ka! Ẹ tu ka!”. Leyin naa ni won yoju si moto ti Dr. Sekinat wa. Won bere si ni fifa fila, fifa bante, won si n bu u lasan.

Ninu igbiyanju lati daabobo ara re, ni won gbá a, won si fa gèlè to wọ lori ni danu si ile. Eniyan bi mejila ti o wa nibe so pe ti awon toogi naa ba ni anfaani, won iba ti pa obinrin naa.

 

BÍ ỌLỌHUN ṢÉ GBA A LỌWỌ IKÚ

Oro naa ti di ariwo ni gbogbo ìlú Ede. Awon odo onigboya ati awon agba ilu ni won sare jade, won fi igboya gba obinrin naa lowo awon toogi naa. Won sì dáàbò bò lọ́wọ́ àwọn toogi náà, awon eeyan rere naa ni won gbe e sori moto, ti won fi iyara gbe e lo si ile iwosan aladani kan to wa nitosi ibẹ.

Iroyin ayo ti o wa lowo wa lati ile iwosan naa ni pe:

“O ṣeun Oluwa, ori ko yọ. Ẹmi re wa. Egbo kekere pere la ni lara, awon dokita si n tọju re dada, o si ti n sọrọ.”

 

Titi di asiko yi, egbe APC ti ipinle Osun ko ti soro lori isele ibaje yi, sugbon ibinu lo n jo ni okan awon ololufẹ Bola Oyebamiji.

Okan ninu awon alatilayin re to ba wa soro lori foonu binu gidigidi, o ni “Iwa ọdaju atiwa ni eyi! Kii se oselu omoluabi! A n pe fun olopaa ati DSS ki won mu awon afurasi ti o se isẹ buruku yii, ki ofin si ye won wò!”

A gbiyanju lati kan si ile ise olopaa, sugbon won ko ti dahun.

Bayii, gbogbo ilu Ede wa ninu ifooro ati eru, awon eniyan si n beere pe, se oselu 2026 yi yoo je oselu alaafia ni bi?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.