KÍN LO FÀ GBASS-GBOSS LÁÀRÍN ILEEṢẸ ÀÀRẸ ÀTI ATIKU ABUBAKAR

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Iṣẹgun 4, Oṣù Kẹjọ 2026. 

 

Ariwo tuntun ti buyọ laarin Igbakeji Aare tẹlẹ, Alhaji Atiku Abubakar, ti o jẹ oludije fun ipo Aare labẹ ẹgbẹ ADC, ati Ile-Iṣẹ Aare Bola Ahmed Tinubu lori ipo ti ọrọ-aje orilẹ-ede Naijiria wá.

 

Atiku Abubakar, ẹni ti o jẹ oludije PDP ni idibo 2023, ti fi ẹsun kan ijọba pe eto ọrọ-aje ti Aare Tinubu n mu irora ati ipọnju pupọ ba awọn ara Naijiria, pe ijọba ko mura silẹ to nigba to wọle ni May 2023. O ni iṣe ijọba n fa ki iṣoro ọrọ-aje naa le si i.

 

ÌDÁHÙN BAYO ONANUGA – ILÉÉṢẸ́ ÀÀRẸ 

 

Ni idahun si ọrọ Atiku, Oludamọran Pataki fun Aare lori ọrọ Alaye ati Ilana, Ogbeni Bayo Onanuga, ti dahun gidigidi.

 

Onanuga pe ọrọ Atiku ni “ọ̀rọ̀ tí kò dá lórí òtítọ́” (not grounded on facts) ati pe o da lori aworan atijọ ti itan, kii ṣe déédéé tode-oni.

 

KÍNNÍ ONANUGA SỌ LẸKUNRẸRẸ :

 

1. ÀTÚNṢE ÈTÒ -OKOOWO N ṢIṢẸ: O ni ijọba Tinubu jogun ọrọ-aje to rẹwẹsi gidigidi. Isuna 2023 ti o pada fihan pe 97% owó tó ń wọle lorilẹ-ede lo n lọ fun sisan gbese nikan, owo diẹ tó kú ní fun idagbasoke.

Nitori naa, yiyọ owo iranlọwọ epo (fuel subsidy) lati Ọjọ Kinni ati isokan awọn owo paṣipaarọ (multiple exchange rates) jẹ dandan lati gba orilẹ-ede la.

 

2. ỌJÀ STOCK N GÒKÈ : O ni awọn eto inawo ijọba n mu ere nla wa. Ile-iṣẹ ọja Naijiria (Nigerian Stock Exchange) n ṣe dara ju ti agbaye lọ nitori ere gidi ti awọn ile-iṣẹ n ri, kii ṣe bubble.

 

3. KÒ SI ÒTÍTỌ́ NÍNÚ ỌRỌ ATIKU: O tako ọrọ Atiku pe awọn ile-iṣẹ aladani n dinku ati pe awọn ile-iṣẹ nla ti n kuro ni Naijiria ni ọpọlọpọ. O ni idiyele igbe aye ni Naijiria tun kere ju ti Africa lọ gẹgẹ bi atọka agbaye.

 

4. ÌTÀN TÍTA OHUN-ÌNÍ ORILẸ-EDE: Onanuga fi ẹsun kan Atiku pe eto tita ohun-ini orilẹ-ede (privatization) to ṣe nigba to jẹ Igbakeji Aare labẹ Obasanjo jẹ jibiti nla, to ta ohun-ini fun awọn ọrẹ ati awọn alajọṣepọ rẹ ni owo ti o kere.

 

Onanuga pari ọrọ rẹ pe dipo ki Atiku ma sọ ọrọ lẹnu lasan lati gba olokiki oloselu olowo-poku, o yẹ ki o sọ fun awọn ara Naijiria kini oun funra rẹ iba ti ṣe ti o ba jẹ Aare. O ni Aare Tinubu dojukọ iṣẹ atunṣe orilẹ-ede, Atiku ati awọn rẹ ko le da iṣẹ naa duro.

 

OJB NEWS YORUBA – ÌTÀN | ÌSỌ̀RỌ̀ | ÌGBÓDÒ | ÌMỌ́LẸ̀

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.