Àwọn afurasi mọ́kànlá rèé pẹlu àwòrán Omoyele Sowore

ILEEṢẸ ỌLỌPA KO ÀWỌN AFURASI MOKANLA LÓRÍ ÌKỌLÙ OWOYELE SOWORE AT’AWON ÈÈYÀN RẸ

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Ayoola Bashir, Ado-Èkìtì | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú, 1, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Ileeṣẹ Ọlọpa ipinlẹ Ekiti tí kò àwọn afurasi tí ó din ni mọ́kànlá sì akolo wọn látàrí ìkọlù sì olórí ẹgbẹ́ òṣèlú African Action Congress (AAC) àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọmọyẹlẹ Sowore àti àwọn èèyàn rẹ ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

 

Àwọn afurasi mọ́kànlá tí wọn ní ó lọ́wọ́ nínú ìkọlù sì Owoyele Sowore àti àwọn èèyàn rẹ nile oúnjẹ ìgbàlódé kan nilu Ekiti

 

Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti ti kéde pé wọ́n ti kó afurasi mọ́kànlá tí wọ́n fura pé àwọn ni wọ́n kọlù Sowore àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé oúnjẹ Tawakalitu, ní agbègbè Dalimore ní Ado-Ekiti.

 

Ọkàn lára àwọn olùtẹ̀le Sowore

 

Nínú àtẹ̀jáde tí Alágbàwí fún àjọ ọlọ́pàá náà, SP Abutu Sunday fi síta ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ó ní àwọn ọlọ́pàá apapàndodo Rapid Response Squad (RRS) ló kó wọn níbi ìkọ̀kọ̀ wọn ní agbègbè Atikankan ní Ado-Ekiti ní agogo mẹ́wàá alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọgbọ́njọ Oṣù Kẹwàá, lẹ́yìn tí wọ́n gba ìròyìn ìkọ̀kọ̀.

 

Ọkàn nínú àwọn tí wọn kọlu nilu Ekiti

 

ÀWỌN AFURASI TÍ A KÓ:

Àwọn tí a kó ni yi:

*Joseph Tayo, ọmọ ọdún 32

*Olatunji Abayomi, ọmọ ọdún 41

*Isaac Amba, ọmọ ọdún 22

*Kehinde Ajigbana, ọmọ ọdún 18

*Tosin David, ọmọ ọdún 18

*Solomon Iyanu, ọmọ ọdún 18

*Ogunsola Ayomide, ọmọ ọdún 21

*Ojo Ayodeji, ọmọ ọdún 22

*Kayode Dada, ọmọ ọdún 32

*Segun Olatunji, ọmọ ọdún 28

*Salami Emmanuel, ọmọ ọdún 53

 

Àwọn ọlọ́pàá tún gba nǹkan bíi walkie-talkie méjì, igbó tábà olóró tí a fura pé Indian hemp àti Colorado, ATM card méje, fóònù alágbèéká mẹ́tàlá, àti àwọn nǹkan mìíràn lọ́wọ́ wọn.

 

Ọkàn rèé nínú àwọn alatele Sowore tí wọn kọlu

 

Alákòóso àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti, CP Falade Michael ti fi dá àwọn ará ìlú lóju pé àjọ náà yóò fi gbogbo agbára ṣe ìwádìí, tí wọn yóò sì mú gbogbo ẹni tí ẹ̀bi bá kàn nínú ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́. Ó tún ní àwọn tí wọ́n fara pa, pẹ̀lú Sowore fúnra rẹ̀, ti gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn, tí wọ́n sì ti gba wọn láàyè kúrò níbẹ̀.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ṣé lóòótọ́ nipe ilé igbimọ aṣofin orile-ede Naijiria ń gbìyànjú láti dá àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mìíràn silẹ kún eyii tí ó wà nílè,. *Eyii ni òun ti a mọ nípa rẹ bí àwọn kan ṣe ń sọ pẹlu ó ní ọwọ òṣèlú nínú ni

Polówó ọjà tàbí kí o ṣe ìkéde rẹ pẹlu wá lórí ìkan OJB MEDIAS HUB, pé ẹ̀rọ ibanisoro yíi +2348066952410

 

Kí èyí tó di báyìí, Sowore ti kọ̀ láti gba ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá wọlé, ó ní kò sí ìjà tàbí àríyànjiyàn kankan, bí kò ṣe ìkọlù tí àwọn ọkùnrin tó ní ihò ti ṣe sí òun àti àwọn eeyan rẹ̀ tí wọ́n sì halẹ̀ láti pa òun.

Sowore rèé lakoko to n gba itoju nile ìwòsàn lẹ́yìn ìkọlù naa

Iwadii si n tesiwaju lati mo ipa ti olukuluku won ko ninu ikolu naa.

 

OJB News Yoruba yoo tesiwaju lati fun yin ni iroyin to jinle.

One thought on “ILEEṢẸ ỌLỌPA KO ÀWỌN AFURASI MOKANLA LÓRÍ ÌKỌLÙ OWOYELE SOWORE AT’AWON ÈÈYÀN RẸ”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.