ìdìbò Ọṣun 2026: APC ỌṢUN KO IJAKULẸ, WỌN M’ORI LÈ ILÉ ẸJỌ LÁTI TAKÒ ADELEKE

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje, 17, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti kọ̀ láti gba abajade ìdìbò Gómìnà tó wáyé ní Ọjọ́ Abámẹ́ta 15, Oṣù Kẹjọ, 2026, èyí tí INEC kéde Gómìnà Ademola Adeleke ti ẹgbẹ́ Accord Party gẹ́gẹ́ bí olúborí.

 

Nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n gbé jáde lẹ́yìn ìpàdé pajawiri ní Osogbo, àwọn olórí APC sọ pé:

“A kọ abajade yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe àti ìwà ọ̀daràn wà nínú ìdìbò náà, a sì ń rò láti lọ sílé ẹjọ́ láti díje rẹ̀.”

APC tí olùdíje wọn, Asiwaju Bola Oyebamiji (AMBO) jẹ́, sọ pé wọn ní ẹ̀rí pé ìdìbò náà kò mọ́ tónítóní, àmọ́ àwọn olùfọwọ́sowọ́pọ̀ àti INEC tẹnumọ́ pé ìdìbò náà dára, àwọn ènìyàn Ọ̀ṣun sì ti sọ ohun tí wọ́n fẹ́.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ :

O tan o! Mallam Nosiru El-Rufai ti wọ àjọ ICPC lọ sile ẹjọ́ òní kí wọn ba òun gba 10 Billionu lọ́wọ́ wọn..

Raa káàdì ìpè rẹ tàbí kí ó ra Data èyíkéyìí, kí ó sì sanwo sórí DStv àti Gotv rẹ, bẹẹ lólè ra iná sórí Prepaid meter rẹ pẹlu irọrun lọdọ wá lónìí,, pẹlu ìdíyelé to rọrùn julọ

Gómìnà Adeleke ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ọ̀ṣun, ó sì sọ pé èyí jẹ́ ìṣẹ́gun fún ìjọba tiwantiwa, nígbà tí APC ń múra sílé ẹjọ́.

 

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń retí kí ilé ẹjọ́ pinnu lórí ọ̀rọ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ọdún 2022 nígbà tí Oyetola lọ sílé ẹjọ́ lórí Adeleke, ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ gíga jùlọ fìdí ìṣẹ́gun Adeleke múlẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.