Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Sango-ọ̀tá| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Ẹti, 21, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Ìròyìn ibanujẹ ti wọle si ile iṣẹ wa wipe Pastor Femi, ẹni ti orukọ rẹ tẹlẹ fi wà ninu ariyanjiyan nla pelu ijo Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) ni ọdun 2008, ti dẹrú lórí ayé.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀:
Ni ọdun 2008, wọn fi ẹsun ole jija ile ijọsin kan Pastor Femi. Ohun ti o yanilẹnu ni wipe oun fúnra rẹ je ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ijọ naa, iya rẹ paapaa je oṣiṣẹ ti n fọ igbọnse ni olu ile ijọsin naa.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
Wọn mu un lọ si ọwọ ọlọpaa, wọn si fi ẹjọ sun an. O lo ọdun mẹsan-an (9 years) ni atimọle labẹ “awaiting trial” laisi idajọ. Gege bi awọn alabara rẹ ṣe sọ, iya agbalagba naa bẹ ijọ ati G.O. titi, ṣugbọn kò si esi rere. Lati igbana ni iya naa ti bẹrẹ si ni ṣaisan titi o fi dẹru lori ibusun.
Pastor Femi nigba ti o jade lati ẹwọn, o jade pẹlu arun ọkan ti wọn sọ pe o jẹyọ lati inu iya ti o ri nibẹ.

Idajọ to gbẹhin:
Lẹyin ọdun mẹsan-an, ile ẹjọ da a silẹ, o si ri wipe oun ko jẹbi. Lẹhinna, o lọ si ile ẹjọ lati beere fun owo osu ọdun mẹsan-an ti o ti wa ni atimọle gege bi oṣiṣẹ ijọ. Ile ẹjọ fun un ni aṣẹ, ṣugbọn ijọ naa kọ lati da lóhùn. Lẹyin ọpọlọpọ ariyanjiyan, wọn fun un ni chẹẹki ti wọn ti kọ si ẹyin.
Kini a n beere?
Bó tilẹ jẹ pé a gba laisi gbigba wipe o wa ninu awọn ti wọn fi ẹsun kan, ṣe o yẹ ki a tọju oṣiṣẹ ijọ bayii? Ijọ ti wọn n sọ pe wọn n sin Ọlọrun Ina, ṣe kìí ṣe ki wọn pe ina ba a bi o ba jẹbi dipo lilo eto ọlọpaa ati adajọ ti o le fi eniyan ti mọlẹ fun ọdun mẹsan-an lasan?
Loni, Pastor Femi ti ku. O di oju alaafia.
A n ki idile rẹ ku ewu, a si n duro de alaye osise lati ọdọ idile ati ijọ naa.
Ẹ tẹle wa lori OJB News Yorùbá fun alaye siwaju sii.
