*Egbe APC Fi Iboju Le Obasanjo, Won Tun F’ori Kolu Atiku Lounje!
*Ijoba APC Ni Atiku Ko To Yege Fun Aare Ni 2027
Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje 3, Oṣù Kẹjọ 2026.
Ina oselu tun n jona le Alhaji Atiku Abubakar, Igbakeji Aare Naijiria tele, bi egbe alase All Progressives Congress (APC) se tun fi ohun ibọn si i lana.
Egbe APC ni gbangba ti f’ohun ti Oloye Olusegun Obasanjo, Aare Naijiria tele, sọ nipa Atiku le lori. Obasanjo laipẹ yii ti sọ pe Atiku, ti o ti gbe asia egbe African Democratic Party (ADP/ADC) fun idibo Aare 2027, ko ni agbara ati ero titun ti yoo fi gbe Naijiria laruge.
KÍNNÍ APC SỌ ?
Ninu atẹjade kan ti Agbenuso egbe APC, Felix Morka fi sita ni Abuja lana, o ni:
“Ohun ti Baba Obasanjo sọ naa ni otitọ pata. Obasanjo ti ṣiṣẹ pẹlu Atiku fun ọdun mẹjọ, o mọ ẹni ti Atiku jẹ ju ẹnikẹni lọ. Ti Obasanjo ba ni Atiku ko yẹ, se tani a tun fe bi lere?”
APC ni Atiku ti di eni ti o ti dagba, ti o si ti wa ninu oselu ju ọdun mẹta ọdun lọ, ti ko si ohun titun ti o le mu wa fun awon odo Naijiria. Won ni igbeyawo re pẹlu egbe kọọkan fun idibo Aare ti jẹ ẹri pe o n lepa agbara nikan, kii se ifẹ ilu.
ATIKU KÒ SỌ̀RỌ̀ RÁRÁ?
Titi di asiko ti a nko iroyin yii, ẹgbẹ Atiku ko ti dahun si ọrọ ibinu yii.
Ṣugbọn awọn alatilẹyin rẹ lori ẹrọ ayelujara ti bẹrẹ si ni dahun pe Obasanjo funra rẹ ko ni ẹtọ lati sọrọ, nitori ija ti o ti wa laarin oun ati Atiku lati ọdun 2003.
Idibo 2027 ti n bọ, o daju pe eré orí ìtàgé òṣèlú yoo tun gbona ju bayii lọ.
OJB NEWS YORUBA – ITAN, ISORO, IGBODO, IMOLE
