Ẹ wá gbọ́ túntún: CAPTAIN SUPER EAGLE TẸ́LẸ̀ FI ẸṢIN KRISTẸNI SILẸ DI MÙSÙLÙMÍ ÒDODO

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 30, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Iroyin pajawiri ti o ti wọle ni pe gbajumọ agbabọọlu alafẹsẹgba ọmọ orile-ede Naijiria nni, Captain Super Eagles tẹlẹ William Troost-Ekong (Balogun), ti yipada lati ẹsin Kirisiteeni si ẹsin Isilamu ni orilẹ-ede Qatar!

 

Alaye ti a jẹrisi nipe:

Ni ilu Doha, Qatar, nibiti o ti n gba bọọlu lọwọlọwọ fun ẹgbẹ Al-Ahli ni Qatar Stars League

 

Lẹ́yìn tí wọn ṣe iwenu fún tán ni o ka Shahada (Ẹri Isilamu – “Ko si Ọlọrun miiran afi Allah nikan, ati Anọbi Muhammad ni ojisẹ Rẹ”) ni ede Larubawa, niwaju awọn ẹlẹri

 

Ekong tí di omọ ọdun metalelogbon bayi 33, o darapọ mọ Al-Ahli ni January 2026 lẹhin ti o kuro ni Al-Kholood ti Saudi Arabia

 

Iwe iroyin Qatar Al-Arab ni ọjọ Wednesday, September 23, 2026 lo kọkọ gbé iroyin naa, fidio naa si tan kaakiri lori Facebook oju opo ti ọmọwe Isilamu Dr. Muhammad Salah

Ekong rèé lẹ́yìn tí ó ti di Mùsùlùmí òdòdó

Ninu fidio rẹ tí ó tán káàkiri orí ayélujára ni, Troost-Ekong ni a ri ti o n ka Shahada, ti o n kede igbagbọ rẹ ninu Isilamu.

 

Orísun ìròyìn mìíràn tun sọ pe awọn ọrẹ tí ó jẹ Musulumi nínú ẹgbẹ agbaboolu rẹ ni Qatar ni wọn ṣe iranlọwọ lati ṣafihan Isilamu fun un.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Kínní Igbákejì Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Atiku Abubakar ń béèrè lọ́wọ́ Bọla Ahmed Tinubu lórí gbèsè owó yíya àti èyí tí ó wà nílè tẹ́lẹ̀, àlàyé rèé…

Ta ni William Troost-Ekong?

O jẹ agbabọọlu afẹsẹgba ti o gba bọọlu fun Super Eagles fun ọpọlọpọ ọdun, o jẹ Captain ẹgbẹ naa, o si ti gba bọọlu ni Europe, Saudi Arabia ati bayi ni Qatar. Orukọ iya rẹ ni Balogun (Yoruba)tí ó jẹ ọmọ bibi orile-ede Naijiria, tí baba rẹ jẹ Dutch.

Ekong tí di Mùsùlùmí òdòdó bayi ni orile-ede Qatar

Ohun ti o sọ ninu Shahada:

“Ashhadu an la ilaha illa Allah, wa ashhadu anna Muhammadan Rasulullah”

Itumọ: “Mo jẹri pe ko si Ọlọrun miiran afi Allah nikan soso, ati pe mo jẹri pe Anọbi Muhammad ni ojisẹ Allah”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.