Ẹ JẸ KI N PADÀ SAGBO FÍÌMÙ MI, ÈMI KII ṢE ÀKÀNṢẸ, NKECHI BLESSING SỌ̀RỌ̀ SÓKÈ LẸYIN TO LU’LẸ

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku, 4, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

 

Gbajugbaja oṣere Nollywood, Nkechi Blessing Sunday, ti sọ pe oun yoo pada si iṣẹ fiimu ṣíṣe lẹyin ti oun ati Phyna, aṣáájú eré Big Brother Naija, ja ere idaraya boxing ti awọn gbajumọ.

 

Ninu ere naa ti o waye ni ọjọ Jimọ, Phyna lu Nkechi Blessing lulẹ pẹlu Knockout.

 

Ṣugbọn oṣere naa sọ pe igba akọkọ rẹ ni orí pẹpẹ ija naa jẹ iṣẹ akikanju, nitori oun ko ṣe adaṣe ju ọjọ meji pere lọ ki ere naa to waye.

Nkechi Blessing lu’lẹ̀ lákòókò ìjà pẹlu Phyna

Ninu ohun ti o kọ si ori Instagram rẹ, Nkechi kọ wipe:

“Mo ṣì jẹ CHAMPION laibikita abajade naa… ani afọju mọ ẹni ti o ja bori. Bayi ẹ jẹ ka pada si ṣiṣe fiimu nitori emi ki i ṣe agbó-kùn jija.”

Biotileje pe o ja kúlẹ̀, Nkechi sọ pe oun ṣetan lati tun ja iru ere bẹẹ ni ọjọ iwaju.

 

Ninu àpilẹkọ miran, o kọ wipe: “Ṣe mo tun ṣe eyi lẹẹkansi? OH YES.”

 

O ni oun ko ti gbe ọwọ rẹ soke lati ja ẹnikẹni ri tẹlẹ, ṣugbọn o duro lori pẹpẹ ti oun ko mọ tẹlẹ, o si ja bi jagunjagun.

 

Oṣere naa tun fi iriri naa ṣe iranti iya rẹ to ti papoda, Gloria Obasi Sunday. O ni oun fẹ ki iya rẹ wa nibe, idi niyi ti o fi beere ki wọn kọ orin ayanfẹ iya rẹ ki oun to wọle si pẹpẹ ija.

Ṣé ìpolówó ọjà rẹ lọdọ wá, pé ẹ̀rọ ibanisoro yíi, +2348066952410

Ninu ọrọ rẹ: “Mummy, ṣe o n wo mi? Ṣe o tun gbọ igba ti wọn kọ orin ayanfẹ rẹ? Mo fẹ ki o wa nitosi mi ni mo ṣe beere fun orin naa.”

 

O dupẹ lọwọ Balmoral Promotions ati Bet9ja fun anfaani ti wọn fun un, o si sọ pe iriri naa jẹ ohun ti oun ko ni gbagbe laelae.

 

OJB News Yorùbá

One thought on “Ẹ JẸ KI N PADÀ SAGBO FÍÌMÙ MI, ÈMI KII ṢE ÀKÀNṢẸ, NKECHI BLESSING SỌ̀RỌ̀ SÓKÈ LẸYIN TO LU’LẸ”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.