Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú, 1, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Agba ọ̀jẹ̀ nìdí iṣẹ ère orí ìtàgé Nollywood ilẹ̀ wá nnì, Yemi Ayebo ti gbogbo eniyan mo si Yemi My Lover, ti sọ̀rọ̀ sókè, fi gbé tá lori fidio kan ti akọrin gospel olókìkí nni, Evangelist Tope Alabi se laipẹ yi, nibi ti o ti sọ pe oun Yẹmi my lover lo wa toro rẹ lọdọ Oloogbe Alade Aromire.

Yemi My Lover ni ọrọ naa jẹ́ irọ pipe.
Kini Tope Alabi Sọ Ni Ìbẹ̀rẹ̀?
Ninu itan ti Tope Alabi ti n sọ fun igba pipé, o sọ pe nigba ti òun wa ni Oriire caucus, ibe ni Oloogbe Alade Aromire tí pe e, o ni o ti wa nibẹ fun ọdún pupọ ṣugbọn àwọn wọn o kii n lo oun ninu fiimu, afi nigbati o ba kọrin. O ni Aromire sọ pe oun yoo ko itan kan, ki oun ko orin rẹ. Tope Alabi ni nigba naa ni oun sare lọ ba Yemi My Lover, ti Yemi si lo oun, ti o si kọrin “Atolly Se O gba”.

ṢUGBỌN YẸMI MY LOVER NÍ ÌTÀN YÍ KÒ PÉ.
Esi tuntun lati ọdọ Yẹmi My Lover ṣe àtakò sì ọrọ Tope Alabi ninu iforowero kan ti o se pẹlu Biola Bayo lori Talk To B, ati ninu ọrọ tuntun ti o fi ranse si OJB News Yoruba, Yemi My Lover salaye pe:
“Tope Alabi n pa irọ. Tope Alabi to jẹ ọmọ ọdọ oun ni o koko kàn sẹ́yìn kí ó ti o kuro lọdọ oun lọ ba Alade Aromire. Odidi ọdún mẹta gbako ni o fi n pò yí ọdọ mi kaakiri ki n to gba pe ki o darapọ mọ wa. Mo ro pe ọtí Jesu n pa ni nigbati o soro yi jade lẹ́nu rẹ.”

O tesiwaju pe:
” Tope Alabi jẹ ẹnikan ninu awọn ti o koja lábẹ́ mi ninu iṣẹ yi. A dara fun ara wa. Mo ranti ọdún ti oun tìkára rẹ sọ pe oun ti n wa mi fun odun kan tabi meji. O lo ohun pupo lati ri mi, nigbati o de ile mi mo gba a láàyè nitori pe o ni agbara sise ati ẹ̀bùn orin. Nigba ti o wa lọdọ mi, a ma n lọ si ile wọn ni Oshodi, iya rẹ ti fa le mi lọwọ pátápátá lákòókò naa”.
Yemi tun fi kun pe nigba ti Tope wa lọdọ oun, tálẹ́ńtì orin rẹ ni oun ri, ṣugbọn iṣẹ osere kii se agbara rẹ ju lọ.

IWADI JINLE OJB NEWS – TAA Ni Ọ̀RỌ̀ DÁJÚ?
Iwadi OJB News Yoruba ri pe otito itan Tope Alabi ni asopo meji:
1. Alade Aromire: Ni odun 1994, Tope Alabi pada si iṣẹ tiata, o si darapọ mọ ẹgbẹ́ olokiki “Alade Aromire Theatre Group”. Nibẹ ni o ti gbé orin jade gẹ́gẹ́ bi akọrin ohùn abẹ́nú ère tiata (soundtrack).
2. Yemi My Lover: Tope Alabi tìkára rẹ jẹwọ pe lẹyin ti Aromire pe e, oun sare lọ ba Yemi My Lover. Eyi túmọ̀ si pe o ti wa pẹlu Aromire ki o to lọ si ọdọ Yemi. Sugbon Yemi ni oun ni olùkọ́ àkọ́kọ́ rẹ.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Kini o le fa iyato itan yi? Àwọn àgbà nìdí iṣẹ tiata ni Ipinle Eko salaye fun OJB pe ni awon ọdún 90s, awon osere n yipo lati ẹgbẹ́ de ẹgbẹ́ (caucus). O seese ki Tope ti bẹrẹ lọdọ Yemi, kí o to pada si ọdọ Aromire, tabi idakeji. Kinni kàn ní, àwọn ọdọ tí ó ń gbèrò láti di irawo iṣẹ tiiata yí ṣáá bá máa nnì ọga méjì kí wọn to yàn ọkàn láàyò julọ, Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ gbogbo ẹ julọ ohun ti o ye wa ni pé àwọn mejeji – Aromire ati Yemi – je olukọ rẹ ni igba ibẹrẹ.

Yemi My Lover ti sọ tẹlẹ pe Tope kọjá lábẹ́ rẹ sugbon o gbagbe oun nigba ti o di olokiki, eyi ti o ti fa ariwo lori ayelujara ni January 2024.
ÀFIYÈSÍ :
Ọ̀rọ̀ “Ọtí Jesu n pa ọ” ti Yemi lo jẹ owe Yoruba ti o túmọ̀ si pe eniyan n sọ̀rọ̀ ti ko yege nitori ìgbàgbọ́ ti o mu.
Bi o se wa nisisiyi, Tope Alabi ko ti dahun si esi tuntun yi.
OJB News Yoruba yoo ma boju to oro yi, a si n reti esi lati odo Evangelist Tope Alabi.

One thought on “ÌYÀWÓ MI NI TOPE ALABI, KO TO DI PÉ Ó SA LỌ BÁ ALADE AROMIRE -Yemi My Lover”