OJB IRÒYÌN YORÙBÁ – ÌRÒYÌN ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN | ÌWÁDÌÍ JINLẸ
Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ
Ìdààmú ńlá tí sọ orí àwọn èèyàn àbule Ikosa ni ilu Odogbolu ní Ìpínlẹ̀ Ogún kodò bí Baálè ilé kàn àti ìyàwó rẹ ṣe di èrò ọrùn a remabo lọjọ kan náà, ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfì yìí gbà gbogbo ìlú kàn án lẹ́yìn ikú tókótáyà kan tí kò gbọ́ pé wọn ṣe àìsàn tẹ́lẹ̀ rí, Oloye Kabiru Rasaq tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Amigboro, àti aya rẹ̀, Kehinde Amigboro.
Iṣẹlẹ ai rò tẹ́lẹ̀ yìí wáyé lọ́jọ́ Ẹti, ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹwàá, ọdún 2026, ní abúlé Ikosa, Odogbolu.
Oluwo ifá Amigboro àti aya rẹ
KÍ LO ṢẸLẸ̀ GANGAN?
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí ikọ ìròyìn OJB News Yorùbá ṣe fìdí rẹ múlẹ̀ pé Oloogbe Kabiru Rasaq jẹ́ Oluwo Ifá ìlú Ikosa, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ Babalawo àti oníṣègùn ìbílẹ̀ tó gbajúmọ̀ ní Odogbolu. Ipò Oluwo Ifa jẹ́ ipò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú dídá àbò àti pípamọ́ Ifa, ètò ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀mí ìbílẹ̀ Yorùbá.
Ọ̀rẹ́ kan tó ń jẹ́ Fadipe Gbenro, lójú òpó ìkànnì ayélujára Facebook, ní ó kọ́kọ́ kéde ikú náà ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ó sọ pé “Tọkọtaya méjèèjì fi wá sílẹ̀ lọ́jọ́ kan náà”.
Ṣùgbọ́n ìdí ikú náà ni ó mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ ṣe kàyéfì.
ÌWÁDÌÍ: IṢẸ́ ABẸ TÓ YỌRÍ SÍ ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN
Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ ìwádìí oniroyin ṣe fìdí rẹ múlẹ̀ pé bí ọ̀rọ̀ ikú Oluwo ṣe kó Ìbẹ̀rù àti ẹ̀dùn ọkàn ńlá wọ Odogbolu àti àgbègbè rẹ kò ṣe lẹ́yìn ikú ai ro tí to pa oníṣègùn ìbílẹ̀ naa, Oloye Kabiru Rasaq, tí a mọ̀ sí Amigboro, àti aya rẹ̀ Kehinde, tí wọ́n sọ pé wọ́n kú ní wákàtí díẹ̀ sí ara wọn ní ọjọ́ Ẹti lẹ́yìn ikú ọ́kọ́ tó kọkọ́ wáyé lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí kò ṣe àṣeyọrí.
Oloye Rasaq kú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí kò ṣe àṣeyọrí ní ilé ìwòsàn kan tí wọn kò dárúkọ.
Bẹẹni a gbo pe Ìyàwó rẹ̀ Kehinde ṣubú lulẹ̀ lẹ́yìn tí ó gbọ́ ìròyìn ikú ọkọ rẹ̀ ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà lọ́jọ́ kan náà pẹlu.
“Iṣẹlẹ náà lóòótọ́ wáyé ní ọjọ́ Ẹti, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe gbọ́, Oluwo Ikosa kú lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un ní ilé ìwòsàn kan tí a kò dárúkọ,” ẹni kan tó bá akọroyin wá ṣe sọ̀rọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé mìíràn, bí wọ́n ṣe tufọ̀ ikú ọkọ fún aya rẹ̀ ni obìnrin náà ṣubu, wọ́n sare gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ṣùgbọ́n kò yè é .
Polówó ọjà tàbí kí o ṣe ìkéde rẹ pẹlu wá lórí ìkan OJB MEDIAS HUB, pé ẹ̀rọ ibanisoro yíi +2348066952410
TA NI OLÓÒGBÉ AMIGBORO?
Amigboro kì í ṣe Babalawo lásán. Ó jẹ́ oníṣègùn ìbílẹ̀ tó gbajúmọ̀, olóyè ìbílẹ̀ ní Odogbolu. Ìdílé Amigboro àti Ojurongbe ni ó pàdánù ẹni wọn pàtàkì.
Ìkú rẹ̀ mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí ayélujára bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ oríṣiríṣi:
Àwọn kan ń sọ pé ìbànújẹ́ púpọ̀ ni ó pa aya rẹ̀ – “Àrùn Ọkàn Fífọ́ nítorí ìbànújẹ́ gidigidi”.
Àwọn kan ń béèrè bóyá àrùn kan wà tí ó ń rìn kiri?
Àwọn kan ń sọ pé kí ìjọba ṣe ìwádìí lórí ilé ìwòsàn tí ó ṣe iṣẹ́ abẹ náà.
KÍNI Ó KAN OJB NEWS YORÙBÁ?
Títí di ìsinsìnyí, orúkọ ilé ìwòsàn tí o ṣe iṣẹ́ abẹ náà ṣi wà ní pamọ́. Kò sí àlàyé lórí irú iṣẹ́ abẹ tí o ṣe.
One thought on “Eemọ rèé ó! BAÁLÈ ILÉ KÀN KÚ LOWURO, IYAWO RẸ KU L’ALẸ NI ODOOGBOLU”