Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolanle Kareem, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Ẹti, 30, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ajo to n daabobo awon onibara ni Ipinle Eko, LASCOPA, ti gbe igbese nla lati daabobo ẹtọ awon to n lo ina Ikeja Electric, nibi ti won ti yanju ejo 528 ti awon onibara fi sun, ti won si tun gba owo isanpada ati atunse owo ina to je ₦26,243,758.75 pada fun awon eniyan laarin osu kini si osu kesan odun 2026.
Gẹgẹ bi akosile ajo naa, lapapọ ejo 556 ni won gba lodi si Ikeja Electric (IKEDC) ni osu mesan naa. Ninu eyi, 528 ni won ti yanju, o ku 28 ti o wa lọwọwọ, eyi ti o tumo si pe bi 95% ninu awon ejo naa ni won ti yanju.
Oludari Agba / Alakoso Agba LASCOPA, Afolabi Solebo, Esq., tun tẹnumọ ifaramo ajo naa si didojuko aiṣododo, jijawo awon ileese ina, ati rii daju pe iṣẹ ti o dara de ọdọ awon araalu.

Bi won se n yanju oro náà rèé
Olori Eka Ejo ati Ilaja ti LASCOPA, Mr. Yusuf Musiliu, salaye pe ajo naa n gba ejo nipa ona ori ayelujara ati ni ọfiisi. O ni apejọ ti won n se pẹlu Ikeja Electric ni gbogbo Ọjọbọ to kẹhin oṣu kọọkan ni aye ti awon onibara ati oṣiṣẹ IKEDC ti n jiroro, ti n de adehun alafia.

O gba awon onibara nimoran pe ki won ma lo iwa-ipa tabi gige okun waya, ki won tẹle ilana to tọ. O ni ki won fi awon iwe eri silẹ bi:
*Bilii ina
*Risiti owo ti won san
*Ẹri miiran

Lati le yara yanju oro naa.
Iwadii OJB News Yorùbá:
Iwadii wa fihan pe eyi kii ṣe igba akọkọ. Ni ọdun to kọja, LASCOPA tun gba to ₦186m ni atunse owo bill fun awon onibara Eko lapapọ ninu ẹgbẹrun ejo ti o jẹmọ overbilling ati oro transformer.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Iroyin yi fihan pe ijọba Eko n tẹsiwaju lati fi agbara mu Ofin Idaabobo Onibara ti Ipinle Eko 2025 wá sí ìmúṣẹ (atunse).
LASCOPA tun rọ awon araalu ti o ni ejo lori:
*Owo ina ti o pọju (overbilling / estimated billing)
*Aisi ina to pe
*Iwa aiṣododo miiran lati ọdọ ileese ina
Ki won pe Nọmba ọfẹ: 080 0005 2726 ni ọjọ aje ọsẹ, tabi ki won kọ imeeli si: lasgcopa@gmail.com
Ejo yin yoo gbo, ẹtọ yin yoo bọ!
