Wàhálà ńlá rèé! BÍ ÀWỌN ẸBÍ T’OLUWANI SINGS ṢE KỌ LÁTI SÌNKÚ RẸ, TÍ WỌN NÍ KI WỌN Ò ṢE ÌWÁDÌÍ IKÚ RẸ LÓÒÓTỌ́

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 27, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Wahala ńlá ti bẹ́ sílẹ̀ lórí ìsìnkú gbajúgbajà akọrin ẹ̀mí, Sadiq Olayemi Bayonle tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Toluwani Sings, bí ẹbí baba rẹ̀ ṣe sọ pé kí wọn má ṣe sìn òkú rẹ bai.

 

KÍNI ẸBÍ RẸ̀ SỌ?

Nínú fídíò kan tó ń yí ká lórí ẹ̀rọ ayélujára ní ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ 26 Oṣù Kẹwàá 2026, àbúrò baba rẹ̀ (Uncle) ni ó sọ̀rọ̀ lóyè.

Toluwani Sings nígbà ayé rẹ

Ó ní:

“A pè ìjọba, àwọn ọmọ Nàìjíríà àti àwọn olórí ẹ̀sìn pé kí wọn ran wa lọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ àti tó jẹ́ òtítọ́ lórí ikú Toluwani. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti sin Toluwani títí ìwádìí náà yò fi parí. Ìpinnu ìdílé ni èyí.”

Ìdílé náà tẹnu mọ́ ọn pé kí ìsìnkú náà dúró bẹẹ títí tí wọn yóò fi ṣe ìwádìí lórí irú ikú tó pa á. Wọ́n ní kí wọn má ṣe gbìyànjú láti sìn títí tí wọn yoò fi mọ ohun tó pa á.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

AWUYEWUYE ŃLÁ LÓ ṢẸLẸ̀ LÁÀRÍN ÌJỌBA Ọ̀YỌ́ ÀTI SOUN OGBOMOSO LÓRÍ OYE BALOGUN OGBOMOSO *Ní jọba ipinlẹ Ọyọ bá ní kó sí ọba k’Oba to láṣẹ láti yọ Oloye kan kan nípò

Nínú ọ̀rọ̀ Yorùbá tí ó sọ, ó tún sọ pé gbogbo ẹbí ti pinu pé kí wọn má tí da bá láti sìn lọ́wọ́lọ́wọ́ tí a wà yìí.

Toluwani Sings pẹlu ìyàwó rè

NÍBO NI WỌ́N FẸ́ KÍ WỌ́N SÌ Í?

Àbúrò náà tún sọ ibi tí wọn fẹ́ kí wọn sìn òkú rẹ sì nígbà tí ìwádìí bá parí. Ó ní kí wọn sìn sì àgbàlá ilé tí ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ wà nísinsìnyí ní Ibadan, kìí ṣe ní ojúbọ́ tàbí ní ilé ìjọsìn. Ó ní ẹbí ti ṣetán láti máa san owó mọ́gì fún bó tiẹ̀ pẹ́ tó.

Toluwani Sings nígbà ayé rẹ

AWUYEWUYE MÌÍRÀN TÓ WÀ NÍLẸ̀

Ìwádìí OJB News Yorùbá fihàn pé wahala méjì ló wà:

Nínú ìwádìí wá láti ríi pé wàhálà ńlá méjì ló wà nílè lórí ikú T’oluwani Sings leyi to gba àkíyèsí àti iwadi jinle

1. Ọ̀rọ̀ Ìwádìí Ikú:

Toluwani Sings kú ní ọjọ́ 14 Oṣù Kẹwàá 2026 ní Ibadan. Gẹ́gẹ́ bí PA rẹ̀, Babadunni Gbolabo ṣe sọ, ó ṣubú lulẹ̀ nílé rẹ̀ nígbà tí ó ń múra láti kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé-ìwé, wọ́n sì sọ pé ilé ìwòsàn méje ní Ibadan ni wọ́n kọ̀ láti gba á wọlé kí ó tó kú.

Toluwani Sings pẹlu ìyàwó àti ọmọ rẹ nígbà ayé rẹ

2. Ọ̀rọ̀ Ibi Ìsìnkú:

Baba rẹ̀ gidi, Muniru Adekunle Olayemi, ti bẹ ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé kí ó jẹ́ kí wọn sin ọmọ náà sí ilé tí ó kọ́ tàbí sí abúlé ìdílé, ṣùgbọ́n ìyàwó náà kọ̀, ó ní ojúbọ́ ni.

Toluwani Sings pẹlu ìyàwó rè

OHUN TÍ ÀWỌN ÈNÌYÀN RÍ NÍGBÀ TÍ WỌ́N DÉ ILÉ RẸ̀

Gẹ́gẹ́ bí ẹbí náà ṣe sọ fún wa, nígbà tí wọn dé ilé rẹ̀ ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀, ohun tí wọn rí yà wọ́n lẹ́nu:

“Bí àwọn ènìyàn ṣe ń jẹun, ni wọn ń wo tẹlifíṣàn bí ẹni pé nǹkan kan kò ṣẹlẹ̀ rárá”

Wọ́n ní ìwà yìí ló mú kí wọn fura síwájú sí i, tí wọn sì fẹ́ kí ìjọba wọ inú ọ̀rọ̀ náà.

 

Ní báyìí, ẹbí náà ń bẹ ìjọba, àwọn olórí ẹ̀sìn àti àwọn ọmọ Nàìjíríà pé kí wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ nípa ikú akọrin ẹ̀mí náà kí wọn tó sinmi, kí ẹ̀mí rẹ̀ lè bálẹ̀.

 

OJB News Yorùbá yóò máa tọpinpin ọ̀rọ̀ náà.

One thought on “Wàhálà ńlá rèé! BÍ ÀWỌN ẸBÍ T’OLUWANI SINGS ṢE KỌ LÁTI SÌNKÚ RẸ, TÍ WỌN NÍ KI WỌN Ò ṢE ÌWÁDÌÍ IKÚ RẸ LÓÒÓTỌ́”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.