AWUYEWUYE ŃLÁ LÓ ṢẸLẸ̀ LÁÀRÍN ÌJỌBA Ọ̀YỌ́ ÀTI SOUN OGBOMOSO LÓRÍ OYE BALOGUN OGBOMOSO, ÈYÍ NI OHUN T’ÀMỌ́ NÍPA RẸ

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 27, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Ìjà ńlá ti bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti aafin Soun Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye, lórí ìyọni-po Dokita Saka Adigbite Balogun gẹ́gẹ́ bí Balogun ilú Ogbomoso.

 

KÍNI ÌJỌBA Ọ̀YỌ́ SỌ?

Nínú àtẹ̀jáde tí Kọmíṣánà fún Ọ̀rọ̀ Ìjọba Ìbílẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ Oyè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ademola Ojo fi síta, ó ní Gómìnà nìkan ló ní àṣẹ láti yọ olóye tí ó wà ní ipò gíga bíi ti Balogun kúrò ní ipò.

Ó ní Soun kò ní àṣẹ kankan láti rọ olóye náà ní ipò rẹ̀.

 

Ojo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé abala kẹrìndínlọ́gbọ̀n (Section 49) nínú ìwé òfin tó dé àwọn olóye àti ọba aláyé ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò fún Soun láàyè láti gbé ìgbésẹ̀ yíyọ olóye tí ó wà ní ipò Balogun kúrò, ó ní ìgbésẹ̀ náà lòdì sí òfin.

 

Nítorí èyí, ó ní Dokita Saka Adigbite Balogun ṣì ni Balogun Ogbomoso, ó sì rọ àwọn ènìyàn láti kọjú sí ẹ̀hìn sí ìròyìn pé wọn ti rọ Balogun náà ní ipò.

Soun tilu Ogbomoso pẹlu Balogun ìlú Ogbomoso tí Gómìnà Seyi Makinde sì wá lápá ọtun won

KÍ LÓ FA AWUYEWUYE YÌÍ?

Ìjà yìí bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí aafin Soun Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye fi àtẹ̀jáde kan léde pé àwọn ti ní kí Dokita Saka Adigbite Balogun lọ rọ̀kùn nílé gẹ́gẹ́ bí Balogun ilú Ogbomoso fún ìgbà díẹ̀, láìní gbẹ́dẹ́kẹ.

 

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Balogun náà ni pé ó kọ̀ láti tọwọ́ bọ̀wé ìwé àdéhùn àti ìbúra jíjẹ́ olóòótọ́ sí Soun láti oṣù mẹ́wàá tí wọ́n ti yàn án lóyè.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ọrọ burúkú ń gbòòrò ẹnu bí ìyàn ogún ọdún ṣe fẹ́ máa jó igbakeji Ààrẹ Kashim Shettima lẹ́nu bí àwọn kan ṣe fi ẹ̀sùn kàn. *Eyii ni alaye lori ẹsun tí wọn fi kàn án àti ìdí tì wọn fi gbọdọ yọ kúrò nípò ṣáájú ìdìbò gbogboogbo ọdún 2027.

Nínú àtẹ̀jáde aafin náà, wọ́n ní bíbúwọ́lu ìwé ìbúra àti àdéhùn náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì fún ẹni tó bá jẹ́ olóye Balogun.

 

Wọ́n fẹ̀sùn kan pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìrántí ni àwọn ti kọ ránṣẹ́ sí Balogun náà láti fi rán an létí láti ṣe ojúṣe, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn náà.

 

Èyí ló mú Ọba Olaoye láti pàṣẹ pé kí Dokita Balogun yẹ ara rẹ̀ ní Balogun Ogbomoso mọ́ títí tí wọn yóò fi ṣagbẹ́yẹ̀wò òfin tó dé bí wọn ṣe ní kó lọ rọ̀kùn nílé.

 

ÌṢÀLÀYÉ TUNTUN LÁTI AAFIN SOUN

Gómìnà Seyi Makinde nile Ìjọba ipinlẹ Ọyọ

“A KAN NI KÓ LỌ RỌ̀KÙN NÍLÉ NI, A Ò YỌ Ọ́ NÍPÒ” – Aafin Ogbomoso

Lẹ́yìn àtẹ̀jáde Ìjọba Ìpínlẹ̀ náà, Aafin Ogbomoso tún fi àtẹ̀jáde mìíràn síta láti ṣàlàyé.

Aafin ní wọn kò rọ olóye náà ní ipò, bí kò ṣe pé wọ́n ní kó lọ rọ̀kùn nílé fún ìgbà díẹ̀ ni.

Wọ́n ní èyí lòdì sí ohun tí ó gbà ìgbòro pé Soun rọ olóye náà ní ipò rẹ̀.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ìdí tí wọn fi ní kí olóye náà lọ rọ̀kùn nílé kò sí nù pé kò ṣe ojúṣe rẹ̀ nípa bíbúwọ́lu ìwé ìbúra àti àdéhùn tí àwọn olóye mìíràn ní aafin ti fọwọ́ sí.

“Oṣù mẹ́wàá ni Aafin Soun fi dúró kí olóye Balogun fi buwọ́lu ìwé náà, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti buwọ́lu u. Kàkà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń bu Soun àti ipò ọba Ogbomoso kàákiri, ó sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò dára nípa Soun, èyí ló ṣokùnfà sísọ fún pé kó lọ rọ̀kùn nílé.”

Àtẹ̀jáde náà tẹ̀síwájú pé bí olóye náà ṣe kọ̀ láti buwọ́lu ìwé náà fi hàn pé kò jẹ́ olóòótọ́ sí Soun, àwọn kò sì lè fi aayè gba irú àfòjúdì bẹ́ẹ̀.

 

Ní báyìí, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti yí àṣẹ Soun náà padà, wọ́n sì tẹnu mọ́ ọn pé Dokita Saka Adigbite Balogun ṣì wà lórí oyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Balogun Ogbomoso.

One thought on “AWUYEWUYE ŃLÁ LÓ ṢẸLẸ̀ LÁÀRÍN ÌJỌBA Ọ̀YỌ́ ÀTI SOUN OGBOMOSO LÓRÍ OYE BALOGUN OGBOMOSO, ÈYÍ NI OHUN T’ÀMỌ́ NÍPA RẸ”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.