ẸFUN NI A BI EEDI, BRODA SHAGI FARA GBA Ọ̀TÁ LÉRALÉRA, LO BA TUN GBÀ’DURA FÚN OORE OFE LEEKAN-SI

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olawale Abioduny| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku, 25, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Gbajúgbajà olùṣe siinima apanilẹ́rìn-ín ní Naijiria, Samuel Animashaun Perry, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Broda Shaggi, ti ṣòro sókè ní igboro ayé  lẹ́yìn oṣù mélòó tí ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ pátápátá, ṣugbọn tí orí kò yọ.

Broda Shaggy

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tuntun tí ó gbé sórí ojú-òpó YouTube rẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ 21 Oṣù Kẹwàá 2026, Shaggi sọ bí ọta àkóbá ṣe bà á.

 

Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kẹta ọdún 2026, lákokò tí ó rò pé ọjọ́ iṣẹ́ déédéé ni.

Broda Shaggy nile ìwòsàn

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ:

“A ṣẹ̀ṣẹ̀ parí iṣẹ́ fún ilé-iṣẹ́ kan. A parí yíyàwòrán, a sì ń lọ ní agbègbè Afárá Sango-Ota, nígbà tí ìdíwọ́ ọkọ̀ mú wa. Lójijì, mo gbọ́ ìró bí ìbọn tí ó dún. Gbogbo ibẹ̀ dákẹ́. Mo rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n etí mi kò gbọ́ ohunkóhun. Nígbà tí mo fi ọwọ́ kan ìdí mi, mo rí ẹ̀jẹ̀, nígbà náà ni mo mọ̀ pé ọta àkóbá ti bà mí.”

Shaggi ní ẹ̀rù bà á gidigidi, ó sọ pé ó wọ inú àìlera lẹ́yìn náà, gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ ni kí ó yè.

“Mo wọ inú àìlera títí tí a fi dé ilé ìwòsàn. Ohun kan ṣo tí ó wà lọ́kàn mi ni kí n yè, n kò fẹ́ kú.”

Ó sọ pé nígbà tí wọ́n dé ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ ní agbègbè Alákùkó, Èkó, àwọn dókítà gbìyànjú láti gé aṣọ rẹ̀ láti wá ibi tí ọta náà wọ̀.

Broda Shaggy

Wọ́n padà gbé e lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn ní GRA, Ikeja, nítorí pé ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ ní wọn kò ní ohun èlò tó péye. Níbẹ̀ ni wọ́n ti yára gbé e wọ yàrá pajawiri.

“Nígbà tí a dé ilé ìwòsàn kejì, wọ́n yára, wọ́n gbé mi wọ emergency. Nígbà yẹn, ọkàn mi balẹ̀ pé èmi yóò yè nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.”

 

OṢÙ MÉJÌ NÍLÉ ÌWÒSÀN

Broda Shaggi sọ pé ó lo oṣù mélòó nílé ìwòsàn, kò lè rìn, kò sì mọ̀ bóyá yóò tún lè ṣe àwòrán apanilẹ́rìn-ín mọ́.

“Mo lo oṣù mélòó nílé ìwòsàn, mo rí ara mi bí ẹni tí kò wúlò mọ́. Nígbà tí mo bá rí àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n ń gbe àwòrán sórí ẹ̀rọ ayélujára, omi yóò máa rọ́ ojú mi, nítorí n kò mọ̀ bóyá èmi yóò tún lè ṣe é mọ́. Ẹ̀rù ń bà mí pé àwọn ènìyàn yóò ti gbàgbé mi kí n tó padà.”

Ó pè ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kẹta ní “ọjọ́ kan nínú ayé mi tí n kò fẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá” ó sì pè àkòrí fídíò ìpadàbọ̀ rẹ̀ ní “The Second Chance” – Ànfàní Kejì.

 

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó yè, ó sì ṣe ìlérí fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ pé iṣẹ́ ńláńlá tuntun ń bọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.