Irú kín lè leyii ooo! ÀWỌN BANDIITI JI ỌKÙNRIN KAN ÀTI ỌMỌ OṢÙ MẸ́FÀ PẸ̀LÚ ÌYÁ RẸ GBÉ, WỌN Ń BÉÈRÈ100 MILLIỌNU NÁÍRÀ

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 13, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Ìpayínkeke àti ai balẹ ọkàn tí bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn bàlé ilé ní Ìpínlẹ̀ Kaduna lẹ́yìn tí àwọn banditi apànìyàn jí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ahmed Zakka, aya rẹ̀ àti ọmọ wọn kékeré tí kò tíì ju oṣù mẹ́fà lọ gbé tí wọn sì ń béèrè fún milionu lọ́nà ọgọrun náírà.

 

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí a rí gbà, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀daran yìí wáyé ní agbègbè kan ní Ìpínlẹ̀ Kaduna, níbi tí àwọn banditi náà ti wọlé tọ  ẹbí náà, tí wọ́n sì kó wọn lọ sí igbó tí a kò mọ̀.

Bale ilé àti ọmọ pẹlu ìyàwó tí wọn jọ jí wọn gbe

Ohun tó burú jù nínú ọ̀rọ̀ náà ni pé, àwọn ajínigbé náà ti kàn sí ẹbí wọn, wọ́n sì sọ pé bí wọn kò bá mú 100 Mílíọ̀nù Naira wá fún ìtúsílẹ̀ wọn, wọn máa pa gbogbo wọn dànù.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Wàhálà wá óò bí àwọn ọdọ ìlú Oworonsoki ṣe ń bínú sí àwọn alakoso ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí wọn sì yari mọ wọn lọ́wọ́ pátápátá….

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa sọ pé kí Ìjọba àti àwọn olùdábòbò orílẹ̀-èdè tètè gbé ìgbésẹ̀ kí wọ́n lè gbà ẹbí Zakka kúrò lọ́wọ́ àwọn ajínigbé wọ̀nyí kí wọ́n tó ṣe wọ́n léṣe.

Títí di àkókò tí a fi ń kọ ìròyìn yìí, a kò tíì mọ ibi tí ẹbí náà wà.

 

OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀lé ìròyìn yìí fún yín, ẹ tẹ̀lé wa fún àlàyé síwájú sí i.

2 thoughts on “Irú kín lè leyii ooo! ÀWỌN BANDIITI JI ỌKÙNRIN KAN ÀTI ỌMỌ OṢÙ MẸ́FÀ PẸ̀LÚ ÌYÁ RẸ GBÉ, WỌN Ń BÉÈRÈ100 MILLIỌNU NÁÍRÀ”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.