Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 13, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

*Enikure: AGBARIJO ODO OWORO KORIRA APC
Agbarijo awon odo ni Oworo ti rú ìbínú wọn soke, won ni ẹgbẹ oṣelu APC ro pe awon ara Kosofe ati ara Oworonshoki jẹ ọdẹ àti aláìní laakaye.
Ninu oro kan to n ja kiri lori ikanni ayelujara, nibẹ ni wọn ti fi ẹsun kan ẹgbẹ́ òṣèlú APC pe:
“Ẹ fi igbakeji alaga ijoba ibilẹ yin tẹ́lẹ̀ sori itẹ Oba, fun idi kan lati le awon eniyan ti o gbekele yin jade ni ile ati agbegbe won, ẹ si ro pe ẹyin o sanwo rẹ. Rara!”
Wọn ni ko ye ki ẹ pa eniyan, ki ẹ si sọ ọpọlọpọ di alaini ile, alailaanu, ki ẹ si ro pe ko ni si abajade. Wọn ni abajade naa yoo le gan.

Agbarijo naa tẹsiwaju pe, owo ilu ti wọn ti ji ko ni le fi bo iwa naa mọ, laibikita bi wọn ṣe n na a to.
Wọn ni bi APC ṣe pinnu lati ba aye awujọ awọn ni Oworonshoki ati Kosofe lapapo jẹ, bẹẹ naa ni awọn naa yoo rii daju pe wọn parẹ patapata kuro ni aaye oṣelu agbegbe naa.
Wọn tun pe fun ki a lé awọn aṣoju ti wọn dakẹ, ti wọn n sọ pe wọn ko mọ ohun to n ṣẹlẹ kuro.

Awọn orukọ ti wọn mẹnuba ni:
*Sanni Ganeey Babatunde Okanlawon – Wọn ni ko gbọdọ pada wale, ko si aaye fun eto kẹta kankan.
*Senator Mukhail Adetokunbo Abiru – Wọn pe e ni Senator ti ko ṣiṣẹ, wọn ni o gbọdọ kuro.
*Hon. Kafilat Ogbara – Bi o ṣe fẹẹ sokalẹ, APC ti padanu aaye patapata, wọn yoo parun.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ni ipari oro naa, Agbarijo Odo Oworo ni igbesẹ ti o kàn ni pe: Oworo gbọdọ tunu mọ, alaafia gbọdọ pada!

One thought on “Wàhálà wá óò! ÀWỌN ỌDỌ OWORONSOKI YARI MỌ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC LỌWỌ”