ÈYÍ NI ÀWỌN AKỌNI MÉJE TO LỌWỌ SÍ BI NÀÌJÍRÍÀ ṢE DI ORILẸ-EDE OLOMINIRA

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Lekan Lawal, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Ẹti, 2, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Ko si bí a ṣe fẹ́ sọ ìtàn orile-ede Naijiria tàbí ká ní bí a ṣe fẹ́ máa sọ̀rọ̀ nípa bí Naijiria ṣe gba ominira tí a ní sọ nípa àwọn akọni ẹ̀dá èèyàn tó ronú láti mú wa kúrò lóko àwọn amunisin òyìnbó Gẹẹsi.

 

Bí a ṣe ń ṣe ayẹyẹ ayajo òmìnira ọdún kerindinlaadorin, eyii lomu ikọ iroyin OJB News Yoruba ṣe àgbékalè ìtàn àwọn akọni to ja fún òmìnira tí a wà ń gbádùn rẹ lọjọ toni,ẹni àkọ́kọ́ ni :

 

Oloye Obafemi Awolowo

 

1. OLÓYÈ ỌBÁFẸ́MI AWÓLỌ́WỌ̀ – ASÍWÁJÚ YORÙBÁ

Oloye Obafemi Jeremiah Oyeniyi Awolowo jẹ ọkan pataki lara awọn akọni to ja fitafita fun ominira orilẹ-ede Naijiria.

 

Wọn bi Awolowo ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹta, ọdun 1909 ni ilu Ikenne, ni Ipinlẹ Ogun.

 

Baba rẹ jẹ agbẹ, ṣugbọn o papoda nigba ti Awolowo wa ni ọmọ ọdun mẹwa pere.

 

Awolowo jẹ olufẹ orilẹ-ede to ga, o si ṣe aṣeyọri gidi gẹgẹ bi olori ẹkun Iwọ-Oorun Naijiria. Lara aṣeyọri rẹ ni eto ẹkọ ọfẹ ati itọju ilera ọfẹ fun gbogbo ọmọ ẹkun naa.

 

Ni ọdun 1959, oun ni ẹni akọkọ to da ile-iṣẹ amohunmaworan silẹ ni gbogbo Afirika – WNTV/WNBS. Bẹẹ naa lo da ẹgbẹ Oodua Group silẹ lọdun kan naa fun idagbasoke Yorùbá.

 

O dije fun ipo Aare labẹ ẹgbẹ Action Group ati UPN ni ọdun 1979 ati 1983, ṣugbọn o kù.

 

O fẹ iyawo rẹ, Chief Hannah Idowu Dideolu Awolowo, wọn si bímọ.

 

Papa Awo, gẹgẹ bi ọpọ eeyan ṣe n pe e, jade laye ni ọjọ kẹsan, oṣu karun, ọdun 1987, ni ọmọ ọdun mejidinlọgọrin, ti wọn si sin-in si Ikenne, ilu rẹ. Lati ranti rẹ, ijọba apapọ fi orukọ rẹ sọ Fasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife.

Oloye Olufunmilayo Ransome Kuti

2. OLÓYÈ FUNMILAYO RANSOME-KUTI – IYÁ AFIRIKA

Funmilayo ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Francis Abigail Olufunmilayo Thomas jẹ akinkanju obinrin bi ọkunrin.

 

O jẹ olukọ, olóṣèlú ati ajijagbara to ga julo fun ẹtọ awọn obinrin.

 

Wọn bi i ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹwa, ọdun 1900 ni Abeokuta. Oun ni obinrin akọkọ to lọ si Abeokuta Grammar School, ati obinrin akọkọ to wa ọkọ ayọkẹlẹ ni Naijiria.

 

O jẹ ọkan ninu awọn obinrin akọkọ to ja fun ẹtọ awọn obinrin lati dibo ni Naijiria.

 

Funmilayo ni iya ti awọn akọni mẹta – gbajugbaja olorin Fela Anikulapo-Kuti, Beko Ransome-Kuti ati Ojogbon Olikoye Ransome-Kuti to ti jẹ Minisita fun eto ilera tẹlẹ.

 

Ni ọdun 1978, awọn ọmọ-ogun kọlu ile ọmọ rẹ Fela ti a n pe ni Kalakuta Republic, wọn si ju Funmilayo lati aja kẹta. Ibaje ti o ni ninu iṣẹlẹ naa lo fa iku rẹ ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin, ọdun 1978.

Sir Ahmadu Bello

3. SIR AHMADU BELLO – SARDUANAN SOKOTO

Wọn bi Sir Ahmadu Bello ni ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1910 ni Rabah, Sokoto.

 

O jẹ ọkan gboogi lara awọn aṣaaju akọkọ ni Naijiria ati olori ẹgbẹ Northern People’s Congress (NPC).

 

O ja fitafita lati ri pe Naijiria gba ominira lọwọ awọn oyinbo, lẹyin ti o pada de lati ilẹ Gẹẹsi.

 

Lara ohun ti a fi n ranti Sardauna ni akitiyan rẹ lati so awọn eeyan Ariwa pọ ati lati mu idagbasoke ba wọn.

 

Ijọba fi orukọ rẹ sọ Fasiti Ahmadu Bello, Zaria lati yẹ si.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

#nigeria@66th: eyii ni koko ọrọ méje tí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu sọ nípa Nàìjíríà níbi lọjọ ayajo ọdún òmìnira….

Ẹ wàá gbọ́ túntún oooo bí agbaboolu Super eagle ṣe kó ẹṣin Kristẹni silẹ tó di Mùsùlùmí òdòdó…..

 

Oloye Anthony Enahoro

4. OLÓYÈ ANTHONY ENAHORO – BABA OMINIRA NAIJIRIA

Oloye Anthony Enahoro jẹ ọkan ninu awọn to ja fun ominira Naijiria julọ.

 

Nigba to wa ni ọmọ ọdun mọkanlelogun pere, o di olootu iwe iroyin Southern Nigerian Defender, eyi to mu ki o di olootu iwe iroyin to kere julọ ni itan Naijiria.

 

Enahoro ni ẹni akọkọ to gbe igbero fun ominira Naijiria ni ile igbimọ aṣofin ni ọdun 1953, eyi to mu ki awọn eeyan pe e ni “Baba Ominira Naijiria”.

 

O tẹsiwaju lati ja fun idajọ ododo titi ti o fi jade laye ni ọdun 2010.

Oloye Herbert Marculay

5. OLAYINKA HERBERT MACAULAY – OLUDASILẸ OṢELU NAIJIRIA

Olayinka Herbert Samuel Heelas Macaulay jẹ olóṣèlú, onimọ-ẹrọ, ayaworan ile ati akọroyin.

 

Wọn bi i ni ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun 1864. O tako iṣakoso awọn Gẹẹsi gidigidi.

 

O da iwe iroyin Nigerian Daily News silẹ lati tẹsiwaju ninu oṣelu.

Ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 1923, o da ẹgbẹ oṣelu akọkọ ni Naijiria silẹ – Nigerian National Democratic Party (NNDP).

Macaulay jẹ ẹni ti wọn pe ni oludasilẹ orilẹ-ede Naijiria ode-oni. O papoda ni ọdun 1946.

Oloye Nnamdi Azikwe

6. NNAMDI AZIKIWE – ZIK OF AFRICA

Oloye Benjamin Nnamdi Azikiwe, ti gbogbo eeyan mọ si Zik, ni wọn bi ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1904.

 

O jẹ Gomina Agba Naijiria lati ọdun 1960 si 1963, lẹyin naa lo di Aare akọkọ fun orilẹ-ede Naijiria.

 

Zik kẹkọọ ni ilẹ Amerika ni Columbia, Pennsylvania ati Howard. O pada si Naijiria ni 1934 lati bẹrẹ iṣẹ akọroyin, o si da iwe iroyin West African Pilot silẹ ni 1937.

 

Lara ohun ti a fi n ranti rẹ ni papa ọkọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International Airport ni Abuja, papa-iṣere Nnamdi Azikiwe ni Enugu, ati Fasiti Nnamdi Azikiwe ni Awka.

 

O jade laye ni ọjọ kọkanla, oṣu karun, ọdun 1996.

Alhaji Tafa Balewa

7. ALHAJI ABUBAKAR TAFAWA BALEWA – AARE IJOOBA AKOKO

Wọn bi Alhaji Abubakar Tafawa Balewa ni oṣu kejila, ọdun 1912 ni Bauchi.

 

O jẹ olóṣèlú akinkanju ati Alakoso Agba (Prime Minister) akọkọ ti Naijiria lẹyin ominira.

O ṣiṣẹ pọ pẹlu Sardauna Ahmadu Bello lati da ẹgbẹ Northern People’s Congress (NPC) silẹ.

 

Ni ọjọ karundinlogun, oṣu kini, ọdun 1966, awọn ọmọ-ogun to di itẹgbajọba ṣeku pa a pẹlu awọn adari miran. Lẹyin ọjọ mẹfa ni wọn ri oku rẹ ni agbegbe Eko.

 

Ijọba yẹ si nipa fifi aworan rẹ si owo marun Naira ati sisọ orukọ Fasiti Bauchi di Abubakar Tafawa Balewa University.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.