Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 30, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Iroyin pajawiri ti o ti wọle ni pe gbajumọ agbabọọlu alafẹsẹgba ọmọ orile-ede Naijiria nni, Captain Super Eagles tẹlẹ William Troost-Ekong (Balogun), ti yipada lati ẹsin Kirisiteeni si ẹsin Isilamu ni orilẹ-ede Qatar!
Alaye ti a jẹrisi nipe:
Ni ilu Doha, Qatar, nibiti o ti n gba bọọlu lọwọlọwọ fun ẹgbẹ Al-Ahli ni Qatar Stars League
Lẹ́yìn tí wọn ṣe iwenu fún tán ni o ka Shahada (Ẹri Isilamu – “Ko si Ọlọrun miiran afi Allah nikan, ati Anọbi Muhammad ni ojisẹ Rẹ”) ni ede Larubawa, niwaju awọn ẹlẹri
Ekong tí di omọ ọdun metalelogbon bayi 33, o darapọ mọ Al-Ahli ni January 2026 lẹhin ti o kuro ni Al-Kholood ti Saudi Arabia
Iwe iroyin Qatar Al-Arab ni ọjọ Wednesday, September 23, 2026 lo kọkọ gbé iroyin naa, fidio naa si tan kaakiri lori Facebook oju opo ti ọmọwe Isilamu Dr. Muhammad Salah

Ninu fidio rẹ tí ó tán káàkiri orí ayélujára ni, Troost-Ekong ni a ri ti o n ka Shahada, ti o n kede igbagbọ rẹ ninu Isilamu.
Orísun ìròyìn mìíràn tun sọ pe awọn ọrẹ tí ó jẹ Musulumi nínú ẹgbẹ agbaboolu rẹ ni Qatar ni wọn ṣe iranlọwọ lati ṣafihan Isilamu fun un.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ta ni William Troost-Ekong?
O jẹ agbabọọlu afẹsẹgba ti o gba bọọlu fun Super Eagles fun ọpọlọpọ ọdun, o jẹ Captain ẹgbẹ naa, o si ti gba bọọlu ni Europe, Saudi Arabia ati bayi ni Qatar. Orukọ iya rẹ ni Balogun (Yoruba)tí ó jẹ ọmọ bibi orile-ede Naijiria, tí baba rẹ jẹ Dutch.

Ohun ti o sọ ninu Shahada:
“Ashhadu an la ilaha illa Allah, wa ashhadu anna Muhammadan Rasulullah”
Itumọ: “Mo jẹri pe ko si Ọlọrun miiran afi Allah nikan soso, ati pe mo jẹri pe Anọbi Muhammad ni ojisẹ Allah”
