ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC IPINLE ỌṢUN YỌ ỌWỌ NÍNÚ ẸJỌ TÍ WỌN PÉ ADELEKE

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bade Sulaiman, Osogbo| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Abameta, 12, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Ademola Adeleke Gómìnà ipinlẹ Ọṣun àti onka iye tí ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan mú nínú ìbò ipinlẹ Ọṣun to kọjá

 

Ní báyìí Agbẹjọro Seyi Oyagbile to pe ẹjọ tako esi idibo Gomina ipinle Osun eyi to gbe Ademola Adeleke wọlé fún sáà keji ti fagilé ẹjọ́ naa.

Amofin Oyagbile pe ẹjọ naa lọjọ kẹjọ oṣù Kẹsán an yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ati lorukọ oludije ẹgbẹ naa, Bola Oyebamiji.

Iwe ẹjọ naa ni a gbọ pé wọn lẹ mọ ara patako ni ọọfiisi igbimọ igbẹjọ to ba jẹyọ ninu eto idibo to wa niluu Osogbo, tii olu ilu ipinlẹ Osun.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ọrọ burúkú ń gbòòrò ẹnu bí Gómìnà tẹ́lẹ̀ ni ipinlẹ Kano, Senator Rabiu Musa Kwankwaso ṣe yẹyẹ Atiku ń gbòòrò ayé, kinni òun Kwankwaso sọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ń gbé poyi ẹnu báyìí. Te asopo ìsàlẹ̀ yìí láti kaa síwájú àti síwájú sí nípa ọrọ ti Rabiu Musa Kwankwaso sọ sì Atiku Abubakar

 

Iwe ipẹjọ naa eyi ti akọwe igbimọ igbẹjọ, Belemo Diete-Spiff, buwọ́lù ni nọmba EPT/Osu/Gov/01/2026, ohun si ni ẹjọ ti Asiwaju Oyebamiji ati ẹgbẹ oṣelu APC pe Gómìnà Adeleke ti ẹgbẹ Accord àti àjọ eleto idibo INEC lori esi idibo Gomina ipinlẹ Osun to waye lọjọ kẹẹdogun oṣù kẹjọ to kọja.

Àwòrán agbejoro rèé níwájú olú ileeṣẹ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun

Nọmba to wa lara iwe ipẹjọ keji ni EPT/Os/Gov/02/2026, eyi ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe tako esi idibo Gomina ipinlẹ Osun bakan naa.

Amọ, amofin to pe ẹjọ loruko APC ati oludije rẹ ti wogile ẹjọ naa bayii.

Ẹwẹ, amofin Oyagbile to pe ẹjọ naa sọ fún ìwé iroyin Punch wi pe lóòótọ́ loun ti fagilé ẹjọ́ ọhun.

Ti ẹ o bá gbagbe, igbimọ to n ri si ọrọ òfin ninu ẹgbẹ APC ti sọ ṣaaju tẹlẹ wi awọn o mọ ohun kohun nipa ẹjọ naa.

Oludije fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú ibo Gómìnà ipinlẹ Ọṣun to kọjá, pẹlu Gómìnà Ademola Adeleke tí ipinlẹ Ọṣun pẹlu àmì àjọ eleto idibo INEC

Amofin agba Adekunle Adegoke, SAN fidi rẹ múlẹ pe ko si ẹni to pe ẹjọ tako esi idibo Gomina ipinle Osun lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Adegoke ni igbimọ to n ri si ọrọ ofin ninu APC sepade pọ pẹlú Oyebamiji at’awọn àgbààgbà lẹyìn tí esi idibo naa jade.

Agbẹjọro naa ni ohun tawon fẹnu ko le lori ni wi pe APC ko ni pejọ tako esi idibo ọhun.

O ni ẹgbẹ oṣelu APC gbe ìgbésẹ yii ki alaafia ba le jọba ní ìpínlẹ̀ Osun latari gbogbo rogbodiyan to ti ṣẹlẹ ṣaaju eto idibo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.